Adajọ ti ni ki wọn sọ awọn oṣiṣẹ mẹta to pa ọga wọn sẹwọn ni Kwara

Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ti paṣẹ pe ki wọn sọ awọn oiẹ mẹta kan, Isiaka Sabi, Hassan Bature ati Ardo Umaru, sẹwọn fẹsun pe wọn eku pa ọga awọn agbẹ kan, Jamiu Ibrahim, ẹni ọdun marundinlaaadọta, niluu Idofin Odo-Ashe, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, lọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹfa, ọdun 2022.

 

Tẹ o ba gbagbe, Isiaka Sabi, to jẹ agatu to jẹ oiẹ oloogbe lo lẹdi apo pọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ, ti wọn si lọọ ji ọga wọn gbe sinu oko kan ti ko jinna sile rẹ, ki wọn le ri owo gba lọwọ rẹ, sugbọn nigba ti wọn ko rowo gba lọwọ ẹ ni wọn yinbọn fun un, niyẹn ba ku lojiji.

 

Lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ati ẹgbẹ fijilante n wa Ibrahim kiri ni wọn kan oku ẹ ninu igbo. Lẹyin ọpọlọpọ iwadii ni ọwọ tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta yii, ti wọn si jẹwọ pe loootọ ni wọn eku pa a,ugbọn owo ni wọn fẹ gba lọwọ rẹ.

Lasiko ti wọn e igbẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Agbefọba, Thomas Adebayọ, rọ ile-ẹjọ ko sọ awọn afurasi naa sẹwọn fun odidi ọjọ mọkanlelogun, titi ti wọn aa fi ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Onidaajọ A Mgaji, paẹ ki wọn sọ awọn afurasi ọdaran naa si ọgba ẹwọn Oke-Kura, ni ibamu pẹlu iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ naa. Lẹyin eyilo sun igbẹjọ si ọjọ kin-in-ni, ou Kẹsan-an, ọdun 2022.

Leave a Reply