Adeṣina sọ niwaju igbimọ SARS: Wọn  fọ gbogbo  gilaasi ọkọ mi, bẹẹ ni wọn ji batiri ati redio inu ẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Igbimọ oluwadii tijọba ṣagbekalẹ lati gbọ nipa ifiyajẹni awọn ọlọpaa SARS, awọn ẹṣọ alaabo mi-in atawọn ti dukia wọn bajẹ lasiko rogbodiyan tawọn janduku da silẹ lẹyin iwọde SARS ti ṣekilọ fawọn olupẹjọ.

Ṣe nigba ti igbimọ naa kọkọ jokoo lọsẹ to kọja ni wọn kede pe ẹsun mọkanla lawọn yoo gbọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ṣugbọn ti awọn olupẹjọ kan ko yọju.

Alaga igbimọ naa, Onidaajọ Cornelius Akintayọ, sọ pe igbimọ naa ki i ṣe ṣereṣere rara, yoo si daa tawọn olupẹjọ ati lọọya wọn ba mu nnkan to yẹ ki wọn ṣe lọkun-un-kundun nitori igbimọ naa ni asiko to yẹ ko lo.

Ninu awọn igbẹjọ mọkanla yii, marun-un ni wọn gbọ ninu ẹ, eyi to da lori awọn ọlọpaa tawọn janduku ba mọto wọn jẹ, ti wọn si dana sun tawọn mi-in lasiko ti wọn kọ lu awọn teṣan kan niluu Ikẹrẹ-Ekiti.

Sajẹnti Adeṣina Kọlawọle ni  awọn eeyan naa ba ọkọ Golf 3 toun n lo jẹ, wọn fọ gbogbo gilaasi ẹ, bẹẹ ni wọn ji batiri ati redio inu ẹ, ohun yoo si nilo ẹgbẹrun lọna irinwo naira (N400,000) lati tun un ṣe.

Inspẹkitọ Yakubu Aminu sọ pe wọn dana sun ọkọ Golf 3 toun, eyi towo ẹ jẹ miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna  ọọdunrun (N1.3m) naira.

Leave a Reply