Adekunle ko sọwọ ajọ NSCDC ni Kwara, maṣinni iranṣọ lo lọọ ji ko

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta kan, Adekunle Adeniyi, to n gbe l’Ojule kọkandinlogun, ladugbo Ita-Alamu, niluu Ilọrin, ti ha sọwọ ileeṣẹ NSCDC fẹsun jiji maṣinni iranṣọ meji to jẹ ti Ọgbẹni Kayọde Adeniyi gbe lagbegbe Ọsin-Ọlatunji, niluu Ilọrin.

Alukoro NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa tẹ ọkunrin ọhun pẹlu awọn maṣinni naa.

Afọlabi ni nigba tawọn oṣiṣẹ aabo ẹni laabo ilu da a duro, wọn ri apo kan to ko awọn maṣinni naa si, wọn si beere ibi to ti ri ilọwọ ẹ, ṣugbọn ko le dahun ibeere ọhun geere.

O tẹsiwaju pe iwadii awọn fi han pe afurasi naa lọọ fọ ogiri ṣọọbu kan wọle lo fi ko awọn maṣinni naa, ṣaja foonu, sisọọsi, awọn aṣọ ati bẹẹ lọ.

O ni afurasi naa jẹwọ pe loootọ oun jẹbi ẹsun naa.

Leave a Reply