Adeleke fi ipilẹ ile awọn alalaaji lelẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le mu ki irinajo si ilẹ mimọ Saudi Arabia rọrun fun awọn Musulumi, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti fi ipilẹ ile ti wọn yoo ti maa sinmi, iyẹn Hajj Transit Camp, lelẹ.

Adeleke sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun oun pe ipinlẹ Ọṣun nikan ni ko ni ile awọn alalaaji laarin awọn ipinlẹ to wa niha Iwọ-Oorun Guusu orileede yii.

Nigba to lọ si ibi eto aawẹ Ramadan ti ijọ NASFAT, l’Oṣogbo, gbekalẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lo ṣeleri ilegbee naa fun wọn, o si fi ipilẹ ile naa lelẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn.

Gẹgẹ bi gomina, ẹni ti Kọmiṣanna fun ọrọ iṣakoso labẹle (Home Affairs), Ọgbẹni Rasheed Aderibigbe, ṣoju fun, ṣe ṣalaye, ‘Ki lo de to jẹ ipinlẹ Ọṣun nikan ni ko ni i ni ilegbee awọn ti wọn fẹẹ rin-irinajo mimọ lọ si Mẹka yoo maa de si?

‘Ni bayii ti a ti waa fi ipilẹ ile naa lelẹ, iṣẹ bẹrẹ ni pẹrẹu niyẹn, ko si idaduro mọ, ki inu awọn awọn arinrin-ajo mimọ le dun nigbakuugba ti wọn ba fẹẹ lọ fun Hajj, wọn aa kọkọ sinmi nibi, ko too di pe wọn aa gbera irinajo wọn.

Ijọba mi yoo tun ran awọn arinrin-ajo lọwọ lori ọrọ ọwọngogo gbogbo nnkan to wa lode yii lati le mu ki o rọ wọn lọrun, nitori lara ileri wa ni lati mu nnkan rọrun fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun’

Adeleke waa dupẹ lọwọ gbogbo awọn aṣaaju ẹsin labẹ Imaamu Agba ilu Oṣogbo, to tun jẹ Grand Imaamu funpinlẹ Ọṣun, Sheikh Musa Animaṣahun, fun ifọwọsowọpọ rẹ pẹlu ijọba.

Lara awọn ti wọn wa nibi eto nla naa ni Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, Kọla Adewusi, Akọwe ijọba, Teslim Igbalaye, Timi Ẹdẹ, Ọba Munirudeen Adeṣọla Lawal, Aarẹ fun akojọpọ awọn Musulumi l’Ọṣun, Sheikh Mustapha Ọlawuyi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply