O ma ṣe o, tirela Dangote pa obinrin kan lẹgbẹẹ titi l’Abule-Ẹgba

Faith Adebọla

Ọkọ ajagbe, iru eyi ti wọn fi maa n ko simẹnti lẹbulẹbu, to jẹ ti ileeṣẹ Dangote, ti sọko ibanujẹ sile mọlẹbi abilekọ kan tẹnikẹni ko ti i mọ orukọ rẹ di ba a ṣe n sọ yii. Nibi t’obinrin naa duro si, to n wo ọtun wo osi lati sọda titi ni tirela ọhun ti ya lọọ pa a, to si ku patapata.

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, ọṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, niṣẹlẹ ọhun waye lọna marosẹ Sango si Oṣodi, lagbegbe Abule-Ẹgba, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), ṣe sọ lọjọ Mọnde ọhun, wọn ni ẹgbẹ biriiji Jubilee, lati maa lọ si ileepo Mobil to wa l’Abule-Ẹgba, lobinrin yii duro si, boya o fẹẹ w’ọkọ ni, boya o si fẹẹ sọda titi ni, amọ ibi to wa ọhun ni tirela yii ti ya lọọ gori ẹ mọlẹ, to si pa a nifọna-ifọnṣu.

Atẹjade naa sọ pe bireeki tirela yii lo feeli lojiji, eyi to mu ko ṣoro fun dẹrẹba lati ṣakoso ọkọ ọhun, to fi ya bara sibi ori gọta, nibi tobinrin naa wa.

Ṣa, awọn ẹṣọ LASTMA ti lọ sagbegbe naa, wọn ti yọ oku obinrin ọhun labẹ tirela, wọn si ti gbe e lọ sile igbokuu-pamọ-si nileewosan ijọba kan to wa nitosi.

Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii.

Leave a Reply