Iṣana ti wọn fi n tan gaasi l’Ayinde n lo bii ibọn lati jale l’Ado-Odo

Faith Adebọla

 Beeyan ko ba wo kinni naa daadaa, ibọn gidi ni tọhun yoo kọkọ pe e, tori bii ibọn ni wọn ṣe e, amọ ki i ṣe ibọn, iṣana igbalode ti wọn fi n tanna si gaasi idana ni. Amọ kinni yii ni ogbologboo afurasi ọdaran kan, Oluwatosin Ayinde, sọ di irinṣẹ idigunjale ni tiẹ, lo ba bẹrẹ si i fi dẹruba awọn araalu, o si n ja wọn lole dukia wọn, kọwọ palaba rẹ too segi.

Alukoro ẹṣọ alaabo Ogun State Community, Social Orientation, and Safety Corps, ti wọn tun n pe ni so-safe nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Moruf Yusuf, to gbẹnu ọga agba wọn, Kọmandaati Sọji Ganzallo, sọrọ ninu atẹjade to fi sọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta yii, sọ pe lọwọ alẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ, lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ọhun tẹ Ayinde, lasiko ti wọn n ṣe patiroolu lọwọ.

O ni ẹnikan to kọkọ fi ẹsun iwa ọdaran ọhun to Ọga so-safe agbegbe Agbara, Ọgbẹni Adebẹṣin Lukmọn, leti sọ pe, awọn ajinigbe ti fẹẹ ji ẹnikan gbe, wọn ni ọlọkada lonitọhun, wọn si pe orukọ ẹ ni Abiọdun Ogunbiyi, wọn ni niṣe ni wọn na ibọn si i, wọn gba ọkada rẹ.

Loju-ẹsẹ lawọn ẹṣọ So-Safe sare de ibi iṣẹlẹ ọhun, wọn ba ọlọkada naa nibi to gbe n lọgun pẹlu ọkada rẹ to ṣubu le e mọlẹ, amọ ọlọkada yii ti bu ẹni to yọbọn si i laṣọ so pinpin, ko si sọ aṣọ ọhun silẹ bo ṣe n pariwo, ‘ẹ gba mi o, ẹ gba mi o’.

Ẹnu eyi lawọn ẹṣọ naa debẹ, bi Ayinde si ṣe gboju soke ri wọn lo ju ibọn ọwọ rẹ sigbo rere, amọ wọn wa kinni ọhun kan, ti wọn si ri i pe ibọn ti Ayinde fi n jale yii ki i ṣe ibọn gidi, iṣana igbalode ti wọn n pe ni laita (lighter) gaasi ni, o kan da bii ibọn ni.

Ṣa, wọn fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran yii, wọn si doola ẹmi ọlọkada naa, bo tilẹ jẹ pe o ti fara pa gidi.

Ni ọfiisi so-safe, Ayinde jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ loun, agbegbe Idanyin, niluu Agbara, lo loun n gbe, o lo ti pẹ toun ti n fi laita ti wọn ṣe bii ibọn yii jale kaakiri agbegbe Ado-Odo ọhun. O ni tawọn eeyan ba ti ri kinni ọhun lọwọ oun, toun fi halẹ mọ wọn, oju-ẹsẹ ni wọn n jọwọ dukia wọn f’oun, ti yoo si gba foonu, owo, ṣeeni atawọn nnkan mi-in lọwọ wọn.

Ganzallo ni awọn ti fa afurasi naa le awọn ọlọpaa ẹka Agbara lọwọ lati tubọ ṣewadii ijinlẹ nipa rẹ, ki wọn si le foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply