O ma ṣe o, oludije funpo gomina lẹgbẹ APC Ondo ku lojiji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayeefi patapata lọrọ iku Dokita Paul Akintẹlurẹ, to jẹ ọkan pataki ninu awọn to fẹẹ díje dupo gomina ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ All Progressive Congress, ti ipinlẹ Ondo, ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii, ṣi n jẹ fawọn eeyan titi di ba a ṣe n sọ yii.

Ọkunrin oniṣegun oyinbo ọhun, ẹni to wa lati ilu Igbótako, nijọba ibilẹ Okitipupa, ni wọn lo deedee ku lojiji ni afẹmọjumọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Ọsẹ to kọja ni Akintẹlurẹ pariwo ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ agbẹnusọ rẹ, Ọgbẹni Ọladapọ Akintẹlurẹ, pe awọn eeyan kan n lepa ẹmi oun lati pa.

O ni oun n mọ-ọn-mọ pariwo sita ni, nitori bi ọjọ eto idibo abẹle ẹgbẹ awọn ṣe n sun mọ tosi naa ni ihalẹ awọn ẹni ibi ọhun tubọ n lagbara si i lati pa oun.

Iṣẹlẹ ọhun lo ni oun ti fi to awọn agbofinro atawọn tọrọ kan leti, ti wọn si ti sọ awọn igbesẹ to yẹ ki oun gbe fun oun.

Akintẹlurẹ ni Oloogbe Rotimi Akeredolu mu gẹgẹ bii igbakeji rẹ nigba to kọkọ dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria (ACN) lọdun 2012.

Ilu kan naa, iyẹn Igbótako, loun ati Ṣẹnetọ to ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ondo nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Jimoh Ibrahim, ti wa. Awọn mejeeji ni wọn si jọ fẹẹ dije dupo gomina ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to n bọ lọna.

O ti figba kan dupo aṣofin agba lasiko idibo to kọja lọ yii ko too di pe ipo naa ko bọ si i, to si jẹ pe ọmọ ẹgbẹ PDP lo bọ si lọwọ.

Ileewosan aladaani kan ni wọn ni ọkunrin naa dakẹ si lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Alex Kalẹjaiye ni loootọ ni oloṣelu pataki naa ti dagbere faye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, niluu Eko.

 

Leave a Reply