Nitori ẹsun wiwa kusa lọna aitọ, afurasi marun-un ha ṣakolo EFCC n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, ni awọn afurasi marun-un kan Dauda, Abubakar, Quadri Ọladimeji, Auwal Garba ati Anas wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn wa kusa  lọna aitọ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe laaarin ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, si ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lọwọ tẹ awọn afurasi naa lagbegbe Márábá, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ati Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ri tirela mẹta ti wọn fi n ko  kusa ti wọn n wa lọna aitọ ọhun, nitori pe wọn ko gba aṣẹ lọwọ ijọba.

Dẹrẹba mẹta lo wa ninu awọn afurasi tọwọ tẹ ọhun awọn ni Dauda, Abubakar ati Anas, tawọn mẹtẹẹta si n wa tirela to ni awọm nọmba iforukọ silẹ wọnyi, JJJ 206 YG, Lagos: T24413 LA, Lagos ati KNT 635XP, Niger.

Lasiko ti wọn n ko awọn ohun alumọni bii okuta mabu, atike funfun (white powder), lithium ati lepidolite lati iluu Ilọrin lọ si Sagamu ati Alakija nipinlẹ Ogun ati Eko, ni ọwọ tẹ awọn afurasi ti wọn si n gbero lati lọọ ta awọn ẹru ofin ti wọn ko ọhun leyi ti wọn o ni iwe ẹri.

Ṣaaju lọwọ ajọ EFCC, ti kọkọ tẹ awọn afurasi mọkanlelogoji lọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, pẹlu tirela mejila ti wọn fi n ko awọn ẹru ofin ọhun lai gba aṣẹ lọwọ ijọba nibi ti wọn o ni iwe ẹri.

Ajọ naa ni awọn yoo foju awọn afurasi yii bale-ẹjọ lẹyin ti awọn ba pari gbogbo iwadii.

Aworan awọn afurasi marun-un to ha sakolo EFCC n’llọrin ree

Leave a Reply