Amọtẹkun le oṣiṣẹ wọn mẹta danu l‘Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn oṣiṣẹ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo mẹta ni iṣẹ ti bọ lọwọ wọn nitori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan wọn lasiko ti wọn wa lẹnu iṣẹ.

Alakooso ẹṣọ ọhun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo fidi eyi mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ta a wa ninu rẹ yii.

Adelẹyẹ ni o ni ofin ati ilana to de jíjẹ ẹṣọ Amọtẹkun, ti awọn si maa n gbiyanju loorekoore lati tẹ awọn ofin wọnyi mọ awọn oṣiṣẹ leti pẹlu ijiya to rọ mọ wọn.

Ṣe ni ọga yii kọ jalẹ lati sọ iru ẹṣẹ ti awọn mẹtẹẹta ṣẹ ki wọn too di ẹni ti wọn n le danu lẹnu iṣẹ. Ohun to ṣaa n tẹnu mọ fun wa ni pe, gbogbo awọn ọmọ abẹ oun ni wọn mọ ofin to de wọn pẹlu ijiya to rọ mọ ọn.

O ni ki i ṣe inu ẹgbẹ Amọtẹkun ni gbogbo ilẹ kaaarọ-o-o-jiire ni eyikeyii ninu ẹṣọ Amọtẹkun ti le maa ṣe ohun to wu wọn.

O ni ki i ṣe pe awọn gba iṣẹ lọwọ awọn mẹta ọhun nikan, gbogbo wọn lo ni awọn yoo tun jẹ niya pẹlu, ko le jẹ ẹkọ fun ẹnikẹni to le tun fẹẹ dan iru iwa ti wọn hu wo.

Leave a Reply