Ija buruku laarin Portable ati Bobrisky, eyi lohun to fa a

Monisọla Saka

Ko ti i sẹni to mọ ẹni ti yoo pari ija buruku to n lọ laarin gbajumọ ọkunrin olorin taka-sufee ilẹ wa nni, Habeeb Okikiọla Badmus ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable Zaazu Zeh, ati gbajumọ ọkunrin to maa n pera ẹ lobinrin, Idris Okunẹyẹ, ti wọn n pe ni Bobrisky.

Ija buruku ti wọn ti n sọ ọrọ alufanṣa, ti wọn si n gbera wọn ṣepe rabandẹ rabandẹ yii waye, latari ami-ẹyẹ ati ẹbun owo ti wọn fun Bobrisky, nibi ayẹyẹ afihan fiimu tuntun ti Ẹniọla Ajao ṣẹṣẹ ṣe, eyi to waye lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Oniruuru awuyewuye lo bẹ silẹ lẹyin ti wọn kede Bobrisky gẹgẹ bii obinrin to mura daadaa ju lọ. Ọpọlọpọ eeyan ni ko fara mọ ohun tawọn adari eto naa ṣe. Ọkan lara awọn to jade sita sọrọ pe ami-ẹyẹ naa ko tọ si Bobrisky ni Portable.

O sọ ọ pẹlu yẹyẹ pe, “Ṣebi gbogbo eeyan lo mọ pe ọkunrin ni Bobrisky? Ṣebi ayederu obinrin ni i ṣe. Pẹlu gbogbo awọn arẹwa obinrin to n ṣe tiata to wa nibẹ lọjọ yẹn, o ṣe maa jẹ Bobrisky ni wọn maa mu pe oun lobinrin to daa ju, Bobrisky to jẹ pe owo lo fi ṣe idi…”.

Ọrọ ti Portable sọ yii lo bi Bobrisky ninu, ti awọn mejeeji fi gbomi ija kan pẹlu bi wọn ṣe n fi ohùn ara wọn ti wọn ka silẹ ranṣẹ.

Bobrisky lo kọkọ fesi si ohun ti Portable sọ nigba to ni, “Oloriburuku ologo ana, aṣiere, ṣe emi jọ awọn to o n gbe kiri ni? Abi emi jọ awọn oloriburuku ti o n fun lowo ni? Aye ẹ dẹ maa bajẹ ni. Aye iya ẹ, baba ẹ, gbogbo yin jọ maa ṣofo ni. Oloriburuku jatijati aṣiere, emi maa gbe iya ẹ, wọn o dẹ ni i ri ẹ mọ. Ma a gbe iya ẹ, nibo lo ti lọ, ṣebi wọn gbe ẹ, wọn tu ẹ silẹ ni, emi aa gbe iya ẹ, wọn o ni i ri iyalaya ẹ mọ.

” Pinnock ni mo n gbe, lọọ wadii iye ti wọn n talẹ ni Pinnock, bẹrẹ 460million ni. Ṣe emi jọ ibi to o n gbe to da bii ile ooṣa ni..?

“O ri mi ti mo gbe ibi ti Polanco ti fi mi ṣe aṣoju sori ayelujara, oloriburuku ẹ lọ n ba wọn sọrọ labẹlẹ pe ki wọn yan ẹ bii aṣoju wọn. Ti n ba raaye tiẹ, ma a wọ ẹ, ma a tun gbe iya ẹ. O o ni kuure, awọn ọmọ to o n bi kiri to o le tọ wọn… Awọn ọmọ biliọnia, ọmọ gidi n sọrọ, awọn ọmọ inu gọta bii tiẹ, olooorun ti ki i fọnu n sọrọ…”

Lai jẹ ko tutu, ni ọkunrin idaamu adugbo yii naa fun Bobrisky lesi. O ni, “Iyẹn iwọ…? Nibo lo fẹẹ ran mi lọ ti mi o ti i de ri? Ki i ṣe iwọ lo n huwa ti ko daa ni? Iwọ kọ lo n ba ọkunrin bii tiẹ sun ni? Iwọ to o ni nnkan ọmọkunrin, ọkunrin bii temi ni ẹ, bakan naa ni wa. O sọ ara ẹ di obinrin, o tun n ba ọkunrin ẹgbẹ ẹ lo pọ, O maa ṣẹwọn, abi o ya were? Emi o ran ẹ, ma a tu ẹ fo tan, ma a tu ẹ sita pe iṣẹ aṣẹwo lo n ṣe. Ọkunrin ni Ọlọrun da ẹ, oloriburuku, o o ni i jere, aṣẹwo. O fowo sọ ara ẹ di obinrin, o fowo ṣe idi ati oju, o waa lọọ gba ami-ẹyẹ obinrin to mura ju. Ṣe obinrin ni ẹ ni?

“Jẹ ki wọn ja ẹ sihooho, ṣe o le ṣi igẹ̀? Ṣe o le ṣi igbaaya ẹ, ko o ṣi igẹ̀ si mi? Abi ki i ṣe pe wọn n ba ẹ sun ni wọn fi n fun ẹ lowo ni? Ma a tu aṣiri ẹ, ọlọpaa maa gbe ẹ. Ta ni o mọ? Awọn ti o mọ fẹẹ mọ emi ni, emi ọmọ ologo, emi ọkunrin takuntakun. Ọkunrin ni mi, mo ni nnkan ọmọkunrin mi, ọmọọya mi, emi o yira mi pada. Inu mi dun pe mo jẹ ọkunrin. Iwọ n pe mi ni onidọti, ki i ṣe iwọ ni o ko mọ́, ti ọkan rẹ naa ko mọ ni? Emi lo fẹẹ wọ lori ayelujara? Ko sibi to o n wọ mi lọ, a maa yanju ẹ. Iwọ ni wọn maa ti mọle, iwọ ẹran to yẹ ki wọn so lokun pa. Ta lo bi ẹ, ki ni orukọ baba ẹ? Fun wa ni deeti ọjọ ti wọn bi ẹ, ka le mọ boya ọkunrin ni ẹ tabi obinrin.

“Iwọ wa n sọ pe wa a ti mi mọle? Awọn ti iwọ mọ n jẹ dodo temi ni. Emi ọmọ ologo, mi o ki i bẹ ẹnikẹni lati fẹran mi, ṣe emi ni mo kọkọ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ẹ labẹ aṣọ ni? Ṣebi iwọ yii naa lo kọkọ bẹrẹ.”.

Yatọ si gbogbo ohùn ti wọn n fi ranṣẹ sira wọn yii, oriṣiriṣii ọrọ kobakungbe ni wọn tun n kọ ran ni sira wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ija yii n dun mọ awọn eeyan ori ayelujara, ti ero to wa lẹyin Portable si ju ti Bobrisky lọ, bo tilẹ jẹ pe ohun lo kọkọ bẹrẹ, ohun kan ṣoṣo tawọn eeyan n tẹnu mọ ju ni pe ko yẹ ki Bobrisky maa ṣepe buruku fawọn ọmọ Portable.

Wọn ni baba lo ṣẹ, ko yẹ ko da ti tawọn ọmọ ọlọmọ si i, nitori epe naa ti pọ ju.

Eyi lo mu ki ọkan lara awọn to bimọ fun Portable, ti wọn n pe ni Honeyberry jade sita sọrọ.

O ni, “Uncle Bobrisky, nnkan kan ko gbọdọ ṣe ọmọ mi o. Ẹni tẹ ẹ n ba ja ni kẹ ẹ gbaju mọ. Ewo ni ti pe awọn ọmọ maa ku. Emi ki i ri agbalagba fin o, ẹ ma jẹ ki n woju yin o. Njẹ ẹ mọ bi ọrọ ọmọ ṣe ri lara? Ṣe irinajo oṣu mẹsan-an waa kere ni? Nigba ti ẹyin o tiẹ ti i bimọ. O rọrun bẹẹ ni ẹyin naa ko ti bi. Ohun ti mo ṣaa mọ ni pe kinni kan ko gbọdọ ṣe ọmọ temi”.

Niṣe lawọn to n runa si i lori ayelujara tun ke si gbogbo awọn obinrin to bimọ fun Portable, pe asiko to yẹ ki iṣọkan jọba laarin wọn ree, ki gbogbo wọn para pọ ṣe fidio lati yẹ epe ti Bobrisky ṣẹ lori ọmọ wọn, ki wọn si dawọ jọ le Bobrisky lori lati gbeja baba awọn ọmọ wọn.

Ija naa ṣi n lọ o, ko ti i sẹni to mọ ibi to maa yọri si.

Leave a Reply