Ọta ilọsiwaju lawọn ti wọn maa n ba dukia ijọba jẹ lasiko rogbodiyan – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Minisita tẹlẹ fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe iwa ti ko bojumu ni bi awọn kan ṣe maa n lo anfaani asiko rogbodiyan lati fi ji dukia tabi ba dukia ijọba jẹ. O ni ohun to yẹ ko jẹ ojuṣe akọkọ fun gbogbo ọmọ orileede Naijiria ni lati daabo bo dukia ijọba nibikibi ti wọn ba wa, nitori eyi ni ọpakutẹlẹ si iṣakoso to duroore.

Arẹgbẹṣọla sọrọ yii niluu Oṣogbo, nibi ikojade iwe kan ti wọn pe akori rẹ ni ‘Iṣepataki mimojuto awọn dukia ijọba’ eleyii ti Ọgbẹni Niyi Ọlanipẹkun kọ. O ni ẹnikẹni to ba ri ara rẹ gẹgẹ bii ọmọ orileede tootọ gbọdọ daabo bo dukia ijọba.

Gomina ana nipinlẹ Ọṣun sọ siwaju pe bii ipa to n pa ara rẹ, ṣugbọn to n pariwo pe oun n pa aja ni ki ẹnikẹni maa ba dukia ijọba jẹ nigba ti wahala ba bẹ silẹ.

O ni aṣepamọ ni gbogbo rẹ, nitori gbogbo ilu naa ni yoo jẹ iya atubọtan irufẹ iwa bẹẹ, yoo si fi wọn han gẹgẹ bii ọta ilọsiwaju.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn nnkan bii oju-ọna, omi ati bẹẹ bẹẹ lọ jẹ ohun ti awọn ijọba n mojuto, ṣugbọn to jẹ pe awọn araalu ni wọn n lo o.

“A gbọdọ mọ pe bo tilẹ jẹ pe orukọ ijọba ni wọn kọ si awọn dukia yii, awọn araalu tijọba n sin ni wọn ni wọn. O waa jẹ iyanra-ẹni jẹ fun awọn eeyan lati ji tabi ba awọn dukia yii jẹ lasiko rogbodiyan. Ohun ti ko mọgbọn dani rara ni.

“Loootọ nijọba yoo tun awọn dukia yii ṣe, ṣugbọn pẹlu owo araalu ni, owo to yẹ kijọba na sori nnkan amayedẹrun miiran ni wọn aa na lori atunṣe eyi to bajẹ. Pupọ wọn gan-an lo le ma ṣe e tun ṣe loju-ẹsẹ, awọn araalu a waa maa jiya lẹyin rogbodiyan’

Arẹgbẹsọla gboṣuba fun onkọwe naa fun bo ṣe ko awọn iriri rẹ jọ sibẹ lati le wulo fun awọn to wa lẹnu iṣẹ ati awọn to n bọ lẹyin.

Leave a Reply