Adeleke lo wa nidii iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu l’Ọṣun -Lawal

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, ti sọ pe bi awọn oṣiṣẹ kootu ṣe kọ, ti wọn ko jami lori iyanṣẹlodi ti wọn gun le lati bii oṣu mẹrin sẹyin ko ṣẹyin Gomina Ademọla Adeleke.

Lawal sọ pe ṣe ni gomina n fi ọrọ iyanṣẹlodi naa ṣe oṣelu lati mu ki ohun gbogbo duro daari ni ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun.

Ilu Oṣogbo ni Sooko Lawal ti ṣipaya ọrọ ọhun lasiko to n ba ALAROYE sọrọ. O ni aṣiri pupọ lo wa nidii iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu Ọṣun ọhun, gbogbo rẹ si da lori ọna lati fitina awọn ọmọ ẹgbẹ alatako.

Lawal sọ pe ọrọ yiyọ awọn ọba kan nipo wa lara idi ti Adeleke fi gbe kootu ti pa, nitori ko fẹ ki awọn ọba naa gbe oun lọ si kootu lori igbesẹ to lodi si ofin to gbe.

Bakan naa lo ni awọn ti gbọ iroyin pe laarin ọjọ perete si asiko yii ni gomina yoo bẹrẹ si i fi ọlọpaa ko awọn ọmọ ẹgbẹ APC lori irọ to pa mọ wọn pe wọn gbe mọto to jẹ tijọba lọ.

Lawal sọ siwaju pe gbogbo agọ ọlọpaa to wa l’Ọṣun lo ti kun akunfaya bayii nitori ko si kootu ti wọn fẹẹ ko awọn afurasi lọ, o ni eleyii le yọri si ki awọn ọlọpaa dẹkun lati mu arufin, ki iwa ipa si maa gbilẹ kaakiri nipinlẹ Ọṣun.

O fi kun ọrọ rẹ pe o ti le loṣu kan ti Adeleke ti ṣeleri lati san owo ti awọn oṣiṣẹ kootu ọhun n ba adajọ agba, Onidaajọ Adepele Ojo, ja si, sibẹ, ko paṣẹ fun wọn lati pada sẹnu iṣẹ nitori awọn iṣẹ to fẹẹ lo wọn fun.

O waa ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati da si ọrọ naa ko too di pe onikaluku yoo maa ṣe nnkan to wu wọn nipinlẹ Ọṣun, to si le yọri si aisi eto aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

Leave a Reply