Eyi ni bi eto isinku Akeredolu yoo ṣe lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ẹbi gomina nipinlẹ Ondo tẹlẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu, ti kede ọjọ ti ẹyẹ ikẹyin fun ọkunrin naa yoo waye.

Arẹmọ-kunrin Oloogbe ọhun, Oluwarotimi O. Akeredolu Junior, lo fi ipinnu ẹbi naa lede ninu atẹjade kan to fi sita, eyi to tẹ awọn oniroyin lọwọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Akeredolu kọkọ fi ẹmi imoore rẹ han si gbogbo awọn to duro ti wọn gbagbaagba latigba ti baba wọn ti ku, o ni oun dupẹ lọwọ awọn to ki awọn dele n’Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, nibi ti awọn fi ṣe ibugbe, atawọn to jẹ pe ilu abinibi awọn l’Ọwọ, ni wọn ti lọọ ṣedaro lẹyin baba awọn.

Arẹmọ Aketi ni tọwọ tọwọ ni awọn fi n pe gbogbo eeyan sibi eto isinku baba awọn ti yoo bẹrẹ pẹlu isọji ita gbangba niluu Akurẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Gbagede Democracy Park, eyi to wa lagbegbe Ọja Ọba, l’Akurẹ, lo ni eto yii yoo ti waye ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun. Eto isin nilana ẹṣin Musulumi yoo waye ninu mọṣalasi nla to wa l’Ọja Ọba yii kan naa laago meji ọsan.

Ilu Ibadan, ninu ọgba ileewe girama Loyola, ni wọn ti fẹẹ ṣeto ti ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, níbi ti wọn yoo ti gbe ọkan-o-jọkan awọn eto kalẹ ni iranti Akeredolu, ẹni to ti figba kan jẹ ọkan ninu awọn akẹkọọ ile-iwe ọhun.

Eto iranti yii tun n tẹsiwaju lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, ni olu ile ẹgbẹ awọn akẹkọọ-jade Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lagbegbe Agodi, niluu Ibadan, laarin aago mẹrin si mẹfa irọlẹ. Aago mẹwaa aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ni wọn fẹẹ ṣe akanṣe igbẹjọ ni iranti agba agbẹjọro ọhun, eyi ti yoo waye ni kootu kin-in-ni ninu ọgba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa ni Ring Road, Ibadan.

Lọjọ yii kan naa lawọn ẹgbẹ agbẹjọro tun fi eto ibu-ọla fun ni ti yoo waye ni Iyaganku, Ibadan, ti wọn yoo si kadii ayẹyẹ ọjọ Aje, Mọnde yii, nilẹ pẹlu eto alẹ ibu-ọla fun ni ati orin awọn Onigbagbọ, eyi ti yoo waye ni Jogor Event Centre, Liberty Road, Ibadan, laarin aago marun-un si mẹsan-an alẹ.

Akanṣe eto isin pataki ni wọn yoo fi bẹrẹ ti ọjọ Isẹgun, Tusidee, ti i ṣe ogunjọ, oṣu Keji, eyi ti wọn fẹẹ ṣe ni iranti Aketi ninu ijọ All Saints, Jeriko, Ibadan, yoo waye laarin aago mẹwaa aarọ si mejila ọsan, ti wọn yoo si lọọ pari eto ti ọjọ naa sile Oloogbe to wa n’Ibadan, laago mẹta ọsan.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, lọpọn sun kan etutu ibilẹ Ajabue, eyi ti wọn yoo ṣe niluu Ọwọ, ti i ṣe ilu abinibi Akeredolu, lati fi bọla ikẹyin fun un. Aarin aago mẹsan aarọ si mẹrin irọlẹ, ni wọn fi eto ọhun si. Aago mẹwaa aarọ ọjọ yii kan naa ni wọn fẹẹ ṣeto ijokoo pataki ni iranti Arakunrin ni kootu kin-in-ni to wa ninu ọgba ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, ki wọn too tẹ oku rẹ fun gbogbo aye ri ninu papa iṣere ipinlẹ Ondo to wa l’Akurẹ, laago kan ọsan. Alẹ Ọjọruu, Wẹsidee yii naa, iyẹn laarin aago mẹrin irọlẹ si meje alẹ, ni wọn tun fẹẹ ṣeto ibu ọla fun ni fun un ninu ijọ Andrew Mimọ, to wa ni Ìmọ́là, niluu Ọwọ. L’Ọjọbọ, Tọsidee, ni eto isin asaalẹ Onigbagbọ ninu ijọ yii kan naa, laago mẹrin irọlẹ. Aago mẹjọ alẹ ni wọn fi eto aisun Onigbagbọ ti wọn yoo ṣe nile oloogbe ọhun, eyi to wa ni Maranatha, niluu Ọwọ si, bi wọn ba ṣe n pari lawọn ẹgbẹ ẹlẹmu (Kegites) naa yoo bẹrẹ tiwọn, ti wọn yoo si ṣe e mọju kẹlẹlẹ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun ni wọn fi eto isinku si, inu ijọ Anderu Mimọ yii naa ni wọn yoo si ti ṣe eyi, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ, lẹyin eyi ni wọn yoo lọọ fi ilẹ bo iyooku ara gomina tẹlẹ ri ọhun laṣiiri, nibi ti wọn fẹẹ sin in si. Aago kan ọsan leto wẹjẹ-wẹmu yoo bẹrẹ nile-itura Mildas, loju ọna marosẹ Ikarẹ Akoko, Ọwọ.

Aago mẹta ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, leto bọọlu gbigba ni iranti Aketi yoo waye lori papa iṣere ipinlẹ Ondo, to wa l’Akurẹ, ki wọn too fi idupẹ ti wọn fẹẹ ṣe ninu ijọ Anderu Mimọ laago mẹwaa aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọ kaṣẹ gbogbo eto isinku Aketi nilẹ.

 

Leave a Reply