Joshua yii fo fẹnsi wọ ileeṣẹ kan loru, ọja olowo nla lo ji ko nibẹ

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni afọkansi ni ole jija, ko sẹni toorun ki i kun loru, owe yii lo ṣẹ mọ afurasi adigunjale ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) kan, Ọgbẹni Titus Joshua, to jẹ nnkan bii aago mẹta oru tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, tonikaluku n sun labẹ ọọdẹ rẹ, loun yọ kẹlẹkẹlẹ jade, o dori kọ adugbo New Dawn Garden, lọna Hayat, ni OPIC, to wa niluu Agbara, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, ibẹ lo ti fo fẹnsi wọle, to si ji waya ileeṣẹ kan ka, waya ọhun ki i ṣe kekere rara, ẹru gidi ni.

Ọga agba awọn ẹṣọ alaabo Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps (So-Safe), Kọmadanti Sọji Ganzallo, lo gbẹnu Alukoro wọn, Moruf Yusuf, sọrọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni ta a wa yii.

O ni ọganjọ oru ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, lọwọ tẹ Joshua, lasiko ti oun ati ọrẹ rẹ kan ti wọn jọ lọ ti pari iṣẹ laabi ti wọn lọọ ṣe nileeṣẹ ọhun, iyẹn  Wasco Cable Company, awọn waya ina olowo iyebiye ti wọn fẹẹ ta, atawọn kan ti wọn ri mọlẹ, bo ṣe n hu wọn lo n ka wọn jọ, to si n fi irinṣẹ ti wọn fi n ge waya to mu dani ge e.

Wọn ni lasiko tawọn ẹlẹgiri yii n gbiyanju lati ko awọn ẹru ole ọhun fo fẹnsi jade pada lawọn ẹṣọ alaabo So-Safe ti wọn n sọde kiri kẹẹfin wọn. Amọ nigba ti wọn yoo fi de’bẹ, awọn mejeeji ti bẹ lugbẹ, ọkan sa lọ rau, nigba ti ọwọ pada tẹ Joshua.

Lara awọn ẹru ole ti wọn ka mọ ọn lọwọ ni awọn batiri ọkọ gbẹngbẹ gbẹngbẹ, ti wọn lowo rẹ to ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000), waya ina to nipọn pọnpọnran kan bayii ti wọn n pe ni LT cables, wọn lowo oun to miliọnu lọna ogun Naria (N20m), ati irinṣẹ buruku harksaw ti wọn fi n jale.

Ṣa, wọn lafurasi ọdaran yii ti jẹwọ pe loootọ loun atọrẹ oun n digun jale, wọn si ti fa a le awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ Agbara lọwọ, ki wọn le tubọ ṣewadii to rinlẹ, paapaa nipa bi wọn yoo ṣe ri ekeji rẹ to sa lọ mu.

Lẹyin iwadii, iwaju adajọ ni wọn yoo taari Joshua si, ko le lọọ gba sẹria to tọ si i.

Leave a Reply