Ismail ti rugi oyin, oṣiṣẹ ẹgbẹ ẹ ti wọn jọ n ja lo ku mọ ọn lọwọ

Faith Adebọla

Ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn yii, James Ismail, ti n geka abamọ jẹ lakolo ọlọpaa ipinlẹ Kano bayii, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o paayan. wọn nibi toun ati Ọgbẹni Tukur Adamu ti wọn jọ n ṣiṣẹ nileeṣẹ kan naa ti n ṣe fa-n-fa kan, tọrọ ọhun si pada dija laarin wọn, wọn ni bi Adamu ti ṣubu lulẹ lojiji, gbigbe ti wọn si sare gbe e lọ sọsibitu, ọkunrin naa ko laju saye mọ, o ku patapata.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna Kiyawa, lo fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

O ni, “Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024, ẹnikan pe aago idagiri ileeṣẹ ọlọpaa wa, o fẹjọ sun pe ija nla kan ti bẹ silẹ laarin awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Fas Agro Sacks Company, to wa ni Sharada Ja’in Quaters, niluu Kano, ipinlẹ Kano, ati pe ẹnikan ti ku lasiko ija ọhun, Tukur Adamu lorukọ ẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni, Dango Sharada Ja’in Quaters, lo si n gbe.

“Gbara ti eyi ṣẹlẹ, niṣe lawọn janduku adugbo ọhun fi iṣẹlẹ yii kẹwọ, wọn da rogbodiyan silẹ, wọn si bẹrẹ si i jale, wọn n ko ẹru ẹlẹru, wọn tiẹ fẹẹ dana sun ileeṣẹ naa pẹlu.

“Loju-ẹsẹ ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano, CP Mohammed Usaini Gumel, ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ, ti DPO ẹka Sharada, SP Adamu Abdulrahim, ko sodi, ti wọn si lọ sibẹ, awọn ni wọn sare gbe Adamu lọ ṣọsibitu, ki dokita too fidi ẹ mulẹ pe o ti ku fin-in fin-in.

“A fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran to lu u pa, James Ismail, bẹẹ la tun mu eeyan mẹtala lara awọn janduku ti wọn dana ijangbọn silẹ, a si bomi pana rogbodiyan ọhun.

“Ni bayii, a ti taari awọn afurasi wọnyi si ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran abẹle fun ẹkun rẹrẹ iwadii. Lẹyin iwadii la maa ko gbogbo wọn dele-ẹjọ, ki wọn le lọọ ṣalaye ara wọn.”

Leave a Reply