Daniel yii laya o, lati Ondo lo ti lọọ fi ibọn onike jale n’Ijẹbu

Faith Adebọla

Ọjọ ti pẹ ti wọn ni gende-kunrin kan, Daniel Iwalokun ti n han awọn eeyan agbegbe Ala, nijọba ibilẹ Odogbolu, nipinlẹ Ogun leemọ, ọpọ lo si gbagbọ pe ẹruuku yii ni ibọn lọwọ, ati pe oniṣẹ iku ni, ko sẹni to mọ pe ibọn pompo to fi n ṣe wọn ni ṣuta ki i ṣe ibọn gidi, feeki ni, afi nigba tọwọ palaba rẹ segi laipẹ yii laṣiiri tu.

Ninu alaye kan ti Ọga agba awọn ẹṣọ alaabo, Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps (So-Safe), Kọmadanti Sọji Ganzallo, to gbẹnu Alukoro wọn, Moruf Yusuf, sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lo ti jẹ ko di mimọ pe ọmọ bibi agbegbe Ilajẹ, nijọba ibilẹ Ilajẹ, nipinlẹ Ondo, ni afurasi ọdaran yii, awọn ẹṣọ So-Safe ti ẹka Ijẹbu ni wọn si mu un.

Ninu iwadii ti wọn ṣe, wọn lọkunrin yii jẹwọ pe oun nikan loun n da huwa laabi lagbegbe naa pẹlu ibọn onike ọwọ oun, o n jale, o n lọ ni lọwọ gba, o si n fibọn naa ṣẹru ba awọn ti wọn ba ko sakolo rẹ.

Wọn tun lọpọ igba lo maa n da wahala silẹ laduugbo, to si maa n halẹ pe ẹni to ba ko oun loju yoo kan fiku ṣefa jẹ lasan ni, eyi si ti mu ko di ẹrujẹjẹ sagbegbe ọhun.

Ṣa, awọn So-Safe lawọn ti pari iwadii lori afurasi ọdaran yii, wọn si ti fi oun ati ibọn ọwọ rẹ ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ọbalende, to wa n’Ijẹbu-Ode, fun itẹsiwaju iwadii.

Lati ibẹ ni wọn yoo ti wọ ọ dewaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply