Ayedatiwa gba iṣẹ lọwọ awọn kọmiṣanna Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ti gba iṣẹ lọwọ gbogbo awọn kọmiṣanna atawọn amugbalẹgbẹẹ ti ọga rẹ, Oloogbe Rotimi Akeredolu, yan gẹgẹ bii alabaaṣiṣẹpọ lọdun mẹta sẹyin.

Aṣẹ yii waye ninu atẹjade ti Akọwe iroyin gomina, Ebenezer Adeniyan, fi sita lorukọ Ayedatiwa laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Adeniyan sọ ninu atẹjade ọhun pe gomina ti paṣẹ titu igbimọ iṣejọba ipinlẹ Ondo ka lẹyẹ-o-sọka, aṣẹ yii lo ni ko yọ gbogbo awọn ti wọn jẹ amugbalẹgbẹẹ atawọn olubadamọran gomina ana ọhun silẹ.

O rọ awọn kọmiṣanna ti wọn ṣẹṣẹ gba iṣẹ lọwọ wọn ọhun lati fa eto iṣakoso ileeṣẹ ti wọn n dari le awọn akọwe agba lọwọ kiakia, ki olukuluku wọn si ri i daju pe awọn ko gbogbo ẹru ijọba to wa nikaawọ wọn silẹ ki wọn too lọ.

Gomina Ayedatiwa dupẹ lọwọ gbogbo wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lori idagbasoke ipinlẹ Ondo, laarin asiko ti wọn yan wọn sipo.

 

Leave a Reply