Adesọji Aderẹmi ni arole mi yoo maa jẹ – Ọọni Ogunwusi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Fun ipa rere ati orukọ manigbagbe ti Sir Adesọji Tadenikawo Aderẹmi, ẹni to jẹ Ọọni kọkandinlaaadọta nilẹ Ifẹ, ni lori awọn eniyan nigba aye rẹ, Arole Oduduwa, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, ti ṣeleri pe orukọ baba naa loun yoo sọ arole oun.

Nibi ayẹyẹ iranti ogoji ọdun ti Ọba Aderẹmi jade laye, eleyii to waye ni Ile Oduduwa, lopin ọsẹ to kọja ni Ọọni Ogunwusi ti ṣalaye pe ko si iran Yoruba kankan to le gbọ orukọ Ọba Aderẹmi ti ko ni i kan saara si i nitori laarin ọdun 1930 si 1980 to fi jọba, o la ipa rere.

Loju awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ Ọba Aderẹmi ni Ọọni Ogunwusi ti sọ pe ti awọn oloṣelu asiko yii ba le kọ ẹkọ ifara ẹni ji ati irẹlẹ lara baba naa, aye aa rọrun lati gbe fun gbogbo eniyan.

Lara awọn nnkan ti gbogbo wa ni lati kọ ninu aye Ọba Aderẹmi ni orukọ rere to n fọhun titi di oni, eleyii to san ju wura ati fadaka lọ. Sir Aderẹmi mu idagbasoke orileede yii lọkun-un-kundun.

“Loni-in, amuyangan ni Aderẹmi jẹ fun wa nilẹ Ifẹ ati ni gbogbo agbaye, gbogbo igba la oo si maa ṣeranti wọn. Mo ti ba awọn mọlẹbi sọrọ lori ọna lati sọ orukọ yẹn di manigbagbe, yatọ si pe Adesọji Aderẹmi ni mo maa sọ arole mi”.

Ọkan lara awọn ọmọ Aderẹmi, Ọmọọba Ọwọade Aderẹmi dupẹ lọwọ Ọọni Ogunwusi fun bo ṣe ṣamojuto iranti baba wọn, o ni inu baba awọn aa maa dun lọrun lati ri i pe awọn ọmọ rẹ wa niṣọkan lati ogoji ọdun to ti faye silẹ.

Bakan naa ni Ọbalufẹ ti Ifẹ, Ọba Idowu Adediwura, ẹni to sọrọ lorukọ awọn Ifẹ Traditional Council, kan saara si Aderẹmi fun awọn iṣẹ takuntakun to ṣe lati le mu idagbasoke ba orukọ ilu Ileefẹ kaakiri agbaye.

Ọbalufẹ ṣalaye pe igbesi aye baba naa kun fun ifẹ ati iṣọkan, eleyii to ni o jẹ awokọṣe rere fun gbogbo eniyan.

Ṣaaju ni Ọọni Ogunwusi ti ko awọn mọlẹbi baba naa lọ si oju oori rẹ lati bu ọla fun un, bẹẹ ni wọn tun ṣabẹwo si White House, ti baba naa kọ ni 1937, eleyii ti Ọọni Ogunwusi ti mu rẹwa si i bayii.

Ninu iroyin mi-in, gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla ti ṣapejuwe Adesọji Aderẹmi gẹgẹ bii ọba to dangajia nidii iṣelu ati oṣelu.

Ninu atẹjade lati fi ṣayẹyẹ iranti ogoji ọdun ti baba naa jade laye, Oyetọla ni ọkẹ aimọye idagbasoke lo ba ilu Ileefẹ lasiko baba naa, bẹẹ ni ko gbẹyin rara ninu oṣelu lorileede yii, manigbagbe si ni orukọ atawọn iṣẹ rere to fi silẹ fun iran Yoruba.

Leave a Reply