Adewale Ayuba ṣile olowo nla, o tun di Aarẹ Bọbaṣelu n’Ikẹnnẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n rọjo ikini ku oriire ati adura sile gbajumọ onifuji nni, Oloye Adewale Ayuba, ẹni to ṣile olowo nla niluu Ikẹnnẹ Rẹmọ, lọjọ Ẹti to kọja yii, to si tun joye Ọtunba Aarẹ Bobaṣelu Ikẹnnẹ.

Awoṣifila nile ti Ayuba kọ yii, miliọnu rẹpẹtẹ ni wọn lo pari ẹ, niṣe lo ṣe rekete ti gbogbo ogiri ile ọhun n dan gbinrin.

Ọda funfun ni wọn fi kun un, wọn si fi awọ pupa resuresu (brown) kun apa kan niwaju rẹ. Ile duro lori ilẹ naa lọ ni, bii ẹsiteeti lo ri.

Awọn eeyan sọ pe Ayuba diidi waa fa ile nla yii kalẹ niluu abinibi rẹ ni, nitori ile labọ isinmi oko.

Nipa ti oye Ọtunba Aarẹ Bobaṣelu Ikẹnnẹ ti  Ọba Adeyinka Ọnakade, Alakẹnnẹ Ikẹnnẹ fi i jẹ, Adewale Ayuba dupẹ lọwọ Kabiyesi, gẹgẹ bi ọba paapaa ṣe sọ pe ika to tọ simu la fi n romu lọrọ oye toun fi oṣere yii jẹ.

Adewale Ayuba dupẹ lọwọ gbogbo awọn to waa ba a ṣẹyẹ mejeeji yii, o ṣalaye bi inu rẹ ṣe dun to, o si gbadura pe nnkan ayọ ko ni i tan nile tiwọn naa.

Awọn oṣere ilẹ wa meji, Alaaja Salawa Abẹni ati Ọgbẹni Dele Odule, wa nibi ayẹyẹ ọhun, bẹẹ si lawọn ọtọkulu ilu loriṣiiriṣii wa nibẹ pẹlu.

Awọn pasitọ ijọ Ridiimu ti Adewale Ayuba n lọ lo gbadura sile naa, wọn fi adura ran an lọwọ nipa ti oye to jẹ pẹlu, wọn si fi ohun gbogbo le Oluwa lọwọ fun oludasilẹ Bonsue Fuji, Oloye Adewale Ayuba to ṣile nla, to tun joye tuntun n’Ikẹnnẹ Ereke.

Leave a Reply