Afẹnifẹre ṣayẹyẹ aadọrin ọdun ifilọlẹ ẹgbẹ wọn l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ eeyan ni wọn pejọ sinu ijọ Anglican Dafidi mimọ to wa lagbegbe Oke-Ijẹbu, niluu Akurẹ, lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, nibi tawọn Afẹnifẹre ti ṣayẹyẹ aadọrin ọdun ti wọn ti ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ wọn.

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ ni kete ti wọn pari isin idupẹ ọhun, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ni ayẹyẹ ifilọlẹ ti wọn ṣe lọjọ naa ṣe pataki pẹlu isẹ takuntakun ti ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ṣe ninu eto idagbasoke ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ.

O ni iwuri nla lo jẹ foun pe Ọwọ to jẹ ilu abinibi oun ni wọn ti ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ naa ni nnkan bii aadọrin ọdun sẹyin.

Arakunrin ni ayẹyẹ ti wọn n ṣe ọhun to bẹẹ, o si tun ju bẹẹ lọ, pẹlu ipa ribiribi tawọn aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre ti fi lelẹ lati igba ti wọn ti bẹrẹ.

O ni oun n ba wọn kopa ninu ayẹyẹ naa nitori pe gbogbo igbiyanju wọn latẹyinwa ati lọwọlọwọ lori bi nnkan yoo ṣe dẹrun fawọn ọmọ orilẹ-ede yii ki i sohun to pamọ fawọn eeyan rara.

Lara awọn ti wọn tun wa ni ile-ijọsin ọhun ni gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Olusẹgun Mimiko, Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọnarebu David Bamidele Ọlẹyẹlogun, Alagba Reuben Faṣọranti to jẹ aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre atawọn ọmọ ẹgbẹ mi-in.

Leave a Reply