Afẹnifẹre ko ti i fọwọ si ipo Aarẹ fun Tinubu, Fayẹmi, tabi Tunde Bakare- Yinka Odumakin

Lati tan imọle si awuyewuye to gbode kan lori ẹni ti awọn Yoruba yoo fa kalẹ fun ipo Aarẹ lọdun 2023, Ọgbẹni Yinka Odumakin, ẹni ti i ṣe akọwe ikede fun ẹgbẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre, ti sọ pe ko si ẹni kan bayii laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu tabi Pasitọ Tunde Bakare ti ẹgbẹ naa ti fọwọ si fun ipo ọhun.

Yatọ si awọn mejeeji yii, o ni ẹgbẹ naa ko ti i sọ pe Dokita Kayọde Fayẹmi gan-an lawọn yoo tẹle  fun ipo Aare lọdun 2023.

Ṣiwaju si i, o ni loootọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn aṣaaju nilẹ Yoruba, ṣugbọn ti ẹnikan ba n sọ pe iṣẹ idagbasoke ti ọkunrin naa ṣe fun iran Yoruba ko lafiwe ki i ṣe ootọ rara.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni gbogbo awọn ti wọn lawọn fẹẹ di Aarẹ lọdun 2023 lawọn n wo ohun ti wọn duro fun ati awọn ohun to yẹ lati mọ daadaa nipa wọn.

O ni, “Ẹnikẹni to ba ṣetan lati ṣatunto si eto iṣelu orilẹ-ede yii, lawa ṣetan lati tẹle, bẹẹ ni ẹgbẹ Afẹnifẹre ko ni i kuna lati tẹle ẹgbẹ oṣelu ta a ba fẹ, tabi ẹnikẹni to ba fi ifẹ han lati dije.”

 

Leave a Reply