Afi ki ijọba tete san ṣokoto wọn giri lọdun tuntun yii, ko gbọdọ si awawi kankan mọ-Atiku

Faith Adebọla

Igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan, Atiku Abubakar, ti sọ pe ootọ ọrọ ko le ni ka ma sọ oun, ohun to fiya jẹ wa lorileede yii lọdun to ṣẹṣẹ kogba sile yii ko kọja bi ijọba apapọ ṣe ya ọlẹ, tijọba wọn ko si wuuyan lori rara.

Ninu ọrọ ikini ku ọdun tuntun to fi lede laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii, lori atẹ ayelujara abẹyẹfo (tuita) rẹ lo ti sọrọ ọhun.

Atiku ni oore-ọfẹ Ọlọrun nikan lo jẹ kawọn eeyan le la ọdun 2020 ja, tori ipenija to koju orileede yii lọdun naa ki i ṣe kekere, bijọba apapọ si ṣe fọwọ yọbọkẹ mu nnkan tubọ mu kọrọ naa buru si i.

Sibẹ naa, o ni idunnu nla ni pe a ti gburoo pe wọn ti ṣawari awọn oogun kan to maa dẹrọ arun Korona, wọn si ti ri abẹrẹ ajẹsara fun un lawọn orileede agbaye kan.

O loun reti pe kawọn oogun ati abẹrẹ naa ma pẹ ko too de Naijiria, ki ọkan awọn araalu le balẹ, ki wọn si le pada sẹnu igbe aye wọn bii ti tẹlẹ.

O loun kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ti wọn padanu awọn eeyan wọn lọdun 2020, o si gbadura pe k’Ọlọrun bu ororo itura si ẹdun ọkan wọn, ki Ọlọrun si tu wọn ninu, tori adanu ti ko ṣee diwọn ni.

Atiku ni ko ṣẹṣẹ digba ta a ba n to awọn ipenija ati iṣoro wa lẹsẹẹsẹ, tori gbogbo wa la mọ ibi ti bata ti n ta wa lẹsẹ lẹnikọọkan ati lapapọ, ohun to ṣe koko ni pe ki ijọba tete san ṣokoto lọdun tuntun yii, ki awawi ma ṣe tun jẹ kawọn iṣoro ohun tun bẹre si i mu wa lomi si i.

Atiku gbadura pe kọdun 2021 yii y’abo fun wa, ka si tubọ wa niṣọkan, ki a kun fun adura si Ọlọrun lati ba wa da igba rere pada sorileede yii.

Leave a Reply