Abẹẹ ri Mato, ọmọọdun mẹta lo fipa ba lo pọ

Faith Adebọla

 Akolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, nibi ti wọn ti n ṣewadii awọn oniṣekuṣe atawọn ọdaran abẹle ni Ọgbẹni Mato Yohannah,  ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yii wa, ibẹ ni wọn ti n beere ọrọ lọwọ ẹ fun ti ẹsun fifipa ba ọmọọdun mẹta laṣepọ ti wọn fi kan an.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Ahmed Mohammed Wakil,  to sọrọ yii di mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ yii, sọ pe nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, lawọn lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi naa nile rẹ to wa labule Jimbin, nijọba ibilẹ Ganjuwa, nipinlẹ Bauchi.

O ni adugbo kan naa lọkunrin yii n gbe pẹlu awọn obi ọmọ irinsẹ to han leemọ yii.

Awọn obi ọmọ naa ni wọn mẹjọ Mato lọ si tọlọpaa, nigba ti iya ọmọ ọhun ṣakiyesi ẹjẹ ati ọgbẹ labẹ ọmọ rẹ, ti wọn si bi ọmọ naa leere ohun to ṣe e, lo ba naka si ile Mato.

Nigba ti afurasi naa de teṣan, ti wọn beere bọrọ ṣẹ jẹ lọwọ ẹ, ko tiẹ jampata rara, niṣe lo n fẹyin ọwọ lu ara wọn, o ni loootọ loun ṣe kinni fọmọ naa.

Wọn tun bi i pe o ti to eemelo tiru ẹ ti waye, o ni ko ju eemeji lọ, o nigba tiya ọmọ naa ko si nile, ti wọn ni koun ba wọn mojuto ọmọ ọhun loun huwa agbaaya naa.

Alukoro ọlọpaa ni ọrọ ko wa ẹlẹrii mọ, ole to gbe panla ti jẹwọ, o lawọn ti n palẹ faili ẹjọ afurasi yii mọ, awọn si maa taari ẹ siwaju adajọ laipẹ, ko le lọọ fẹnu ara ẹ ṣalaye aburu to ṣe lọhun-un.

Leave a Reply