Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọgọrun-un kan miliọnu Naira lawọn agbebọn to ji Kazeem Asalapa ati iyawo ọmọ rẹ gbe lagbegbe Gaa-Olobi, Oko-Olowo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, n beere fun.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila aabọ oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn eeyan naa ya bo agbegbe Gaa-Olobi, Oko-Olowo, niluu Ilọrin, ti wọn si n yinbọn leralera. Ni wọn ba wọle tọkọ-taya yii lọ, nigba ti wọn ko ri ọkọ ni wọn gbe baba ati iyawo lọ.
Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn pe mọlẹbi awọn eeyan yii, ti wọn si n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.
Lasiko ti wọn n dunaadura, ti wọn si bẹ wọn pe awọn ko lowo to to iye iyẹn ni wọn gba lati gba miliọnu mẹta Naira.
Nigba ti a pe Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, o ni wọn o ti i fi iṣẹlẹ naa to awọn leti.