Faith Adebọla, Eko
Lasiko ti ọpọ eeyan n ṣe yala-yolo ọdun Ileya, ti wọn n ki ara wọn ku ọdun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, inu ibanujẹ nla lawọn mọlẹbi kan wa, latari ijamba ọkọ ayọkẹlẹ to waye lagbegbe Orile Agege ati ti ọkọ oju-omi to ṣẹlẹ ni Mile 2.
Ọkọ ayọkẹlẹ jiipu SUV kan lo kọkọ taku sinu agbara ojo to kun gbogbo oju titi ni adugbo Ọyatoki, ni Oko-Ọba, Agege, nipinlẹ Eko, eeyan mẹta lo wa ninu jiipu naa. Bo tilẹ jẹ pe jiipu naa pana sinu agbara ọhun, ti ko si ṣee ṣe fawọn to wa ninu ọkọ lati sọ kalẹ, wọn ni niṣe ni igbi omi naa n gbo jiipu ọhun jigijigi, to si n ti i lọ soju koto. Amọ awọn ẹṣọ ileeṣẹ panapana ti ipinlẹ Eko tete de sibi iṣẹlẹ naa, wọn si doola ẹmi awọn mẹtẹẹta.
Ṣe lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to ṣaaju ọjọ ọdun Ileya ọhun ni arọọda ojo ti bẹrẹ lọpọ agbegbe nipinlẹ Eko, nigba to si fi maa di idaji ọjọ Satide, niṣe ni ọwara ojo naa tubọ lagbara gidi, ko si mọwọ ro ṣulẹ ọjọ naa.
Nigba ti ori ko awọn wọnyi yọ, ọrọ ko rọgbọ fun awọn mẹrin ti wọn wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ jiipu Lexus mi-in ni adugbo kan naa. Niṣe ni ọgbara soju ọkọ ọhun de, eeyan meji lawọn gende ti wọn laya, doola ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọhun ki awọn oṣiṣẹ panapana too de, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fara pa, wọn si ti n gba itọju pajawiri lọwọ.
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, wọn ko ti i ri eeyan meji yooku ti wọn jọ wa ninu ọkọ to takiti ọhun, afaimọ ni wọn ko ti bomi lọ, wọn lo ṣee ṣe ki ọgbara ti gbe oku wọn lọ sọna jinjin, tori oju gọta ni ọkọ naa doju de si, ṣiṣi silẹ ni ilẹkun ẹgbẹ mejeeji si wa. Iwadii ṣi n lọ lati ṣawari awọn eeyan meji ọhun.
Ninu iṣẹlẹ mi-in, eeyan mẹrinla lo ṣofo ẹmi ninu awọn mẹrindinlogun ti wọn wọ ọkọ oju-omi ayara-bii-aṣa kan lagbegbe Mile 2 si Ibeshe, laṣaalẹ ọdun Ileya ku ọla, iyẹn lọjọ Furaidee.
Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ku iṣẹju mẹwaa ni wọn ni ọkọ oju-omi W19 Fibre boat ọhun gbera, ko too doju de sinu alagbalugbu ọsa lagbede-meji irinajo naa, lagbegbe Ọjọọ.
Ninu atẹjade kan ti ọga agba ileeṣẹ ọkọ oju-omi ilẹ wa, ẹka ti ipinlẹ Eko, National Inland Waterways Authority (NIWA), Ẹnjinnia Sarat Braimah fi lede lori iṣẹlẹ yii laaarọ ọjọ ọdun Ileya, o ni alẹ ọjọ Ẹti naa lawọn gba ipe pajawiri pe ọkọ oju-omi ọhun ti doju de, kia lawọn ẹṣọ alaabo oju-omi si ti lọ sibẹ, ṣugbọn eeyan meji pere ni wọn ri doola, wọn si tun ri ọkọ oju-omi naa to doju de naa.
Wọn ni iwa aigbọran ni atukọ yii ṣe, tori gbedeke ti wa fun wọn lati ma ṣe tu ọkọ ero lori omi naa kọja aago meje alẹ.
Wọn ni iwadii fihan pe lasiko ti ọkọ naa fi n lọ, igbi omi ti lagbara gan-an lọwọ alẹ naa, ojo si tun n rọ, ẹfuufu yii lo ṣokunfa bi ọkọ naa ṣe doju de.
Wọn tun ni ọpọ lara awọn ero ọkọ naa, paapaa awọn ọmọde, ni wọn ko wọ jakẹẹti idaabobo to le mu ki wọn lefoo loju omi ti ijamba ba ṣẹlẹ.
Wọn lawọn o ti i ri eyikeyii ninu awọn mẹrinla to sọnu naa, boya wọn ti ku somi ni abi wọn ṣi wa laaye, ṣugbọn iṣẹ idoola ẹmi ṣi n tẹsiwaju, atukọ ọhun si wa laarin wọn.
Wọn ti gbe ọkọ oju-omi naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa etido fun iwadii to lọọrin.