Kẹhinde tọwọ ọmọọmọ rẹ bọ omi gbigbona l’Ondo, o lo ji ẹran jẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iya agbalagba, Abilekọ Christianah Kẹhinde, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ niluu Ondo fun ẹsun lilo ọmọ nilokulo ti wọn fi kan an.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye lati inu oṣu Kẹfa, ọdun 2022, laduugbo Abẹjoye, lagbegbe Odo-Ijọka, niluu Ondo.

Mama ẹni ọdun mejilelaaadọta naa ni wọn lo ti ọwọ ọmọọmọ rẹ kan, Suliat Tunde, bọ omi gbigbona lori ẹsun pe ọmọdebinrin ti ko ju ọmọ ọdun mẹjọ lọ ọhun lọọ ji ẹran jẹ ninu ikoko ọbẹ toun se.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun akọroyin wa pe bo tilẹ jẹ pe lati nnkan bii oṣu kan sẹyin ti ọrọ ọhun yii ti sẹlẹ ni ọmọ ta a n sọrọ rẹ ọhun ti wa ninu irora nla, o ni niṣe ni iya agbalagba ti wọn fẹsun kan yii n wo ọmọ naa niran, to si ti i mọle lai bikita ati gbe e lọ sileewosan titi tọwọ ọmọ naa fi n jẹra.

Agbẹnusọ ọlọpaa ọhun ni abilekọ naa ko ri alaye gidi kan ṣe lori idi to fi huwa ọdaju si ọmọ ọlọmọ lasiko tawọn n fọrọ wa a lẹnu wo. O ni ohun kan ṣoso to n tẹnumọ ni pe ṣe loun fẹẹ fi kilọ fun un ko ma baa tun dan iru rẹ wo mọ.

Ọdunlami ni awọn dokita ti kọwe fun ọmọbinrin naa lati lọọ ṣiṣẹ abẹ ni ile-iwosan to wa l’Ondo, nigba ti iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply