Adewale Adeoye
Pẹlu bawọn oniṣẹ ibi ti wọn n pe ni agbebọn ṣe n lọ kaakiri igberiko, paapaa ju lọ, lawọn ipinlẹ l’Oke-Ọya lọhun-un, ti wọn si n paayan rẹpẹtẹ bo ṣe wu wọn, o yẹ kawọn alaṣẹ ijọba orileede Nigeria tete wa nnkan ṣe sọrọ wọn. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, tun ni awọn agbebọn kan lọọ dena de awọn ṣọja ilẹ wa kan lagbegbe Roro, Karaga ati Rumace, to wa ni Wọọdu Bassa, nijọba ibilẹ Shiroro, nipinlẹ Niger, ti wọn si pa mẹfa danu lara awọn ọmọ ogun orileede yii kan ti wọn n ṣiṣẹ sin ilu lọwọ. Yatọ si pe wọn pa ṣọja mẹfa nipakupa lọjọ naa, ṣe ni wọn ji kaputeeni, iyẹn ọga ṣọja kan, Ọgagun Adamu, gbe sa lọ, nibi ti wọn si ji i gbe si ni wọn pa a si, kawọn ọmọọṣẹ rẹ ma baa gba a silẹ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe ṣe lawọn ṣọja naa gba ipe pajawiri lati ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede Naijiria pe ki wọn lọọ doola ẹmi awọn araalu kan. Lasiko ti wọn n lọ lọna lawọn agbebọn ọhun ti lọọ dena de wọn niluu Roro, ti wọn si ṣina ibọn fun wọn. Niwọn igba to jẹ pe lojiji niṣẹlẹ ọhun ba wọn, wọn ko mọ ibi ti wọn maa sa si ni ọta ibọn awọn oniṣẹ ibi naa ṣe pa mẹfa danu lara awọn ṣọja naa, tawọn kan si sa wọgbẹ lọjọ naa.
Yatọ sawọn ṣọja tawọn agbebọn ọhun pa danu, ṣe ni wọn tun pa awọn ọdẹ adugbo meji atawọn agbẹ kan lasiko laṣiigbo naa. Bakan naa ni wọn tun kina bọ awọn oko atawọn dukia awọn araalu.
Araalu kan, Ọgbẹni Mustapha Bassa, to n gbe lagbegbe naa sọ fawọn oniroyin pe fun aimọye wakati lawọn oniṣẹ ibi naa fi n yinbọn soke gbaugbau lati fi da ipaya sọkan awọn araalu ko too di pe wọn sa lọ.
Ogagun to n ri sọrọ eto aabo abẹle nipinlẹ Niger, Bello Abdullah Mohammed, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe loootọ ni awọn agbebọn kan lọọ dena de awọn ṣọja mẹfa kan lasiko ti wọn n lọ fun iṣẹ ilu, ti wọn si pa wọn danu.
Adamu ni awọn n ṣiṣẹ labẹnu bayii lati fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun.