Loootọ ni mo fipa ba ọmọ araalu mi laṣepọ ni baluwẹ, amọ oun lo fa a o – Godwin

Faith Adebola 

Yooba bọ, wọn ni ‘afago kẹyin aparo, ohun oju wa lojuu ri’, owe yii lo wọ ọrọ ọdọmọkunrin to porukọ ara ẹ ni Godwin, pẹlu bo ṣe n geka abamọ jẹ lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii rẹ lọwọ l’Abẹokuta bayii. Ọmọ bibi ipinlẹ Benue ni, o ni ẹya Igede loun, amọ niṣe lo lọọ fipa ba Agnes, ọmọọdun mẹrinla kan laṣepọ, inu baluwẹ lo si ti ṣe ‘kinni’ fun un, lẹjẹ ba n jade loju abẹ ọmọọlọmọ.

Micheal ba Alaroye sọrọ laipẹ yii, o sọ gbogbo bi iṣẹlẹ naa ṣe waye…

‘‘Godwin Friday lorukọ mi. Ọmọ bibi ipinlẹ Benue ni mi, ẹya Igede ni mi, nijọba ibilẹ Oju. Ọmọọdun mọkanlelogun (21) ni mi. Agbegbe Ilọti, niluu Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, ni mo n gbe. Iṣẹ oko riro ni mo n ṣe, mo dẹ tun n ṣe alagbaṣe fawọn agbẹ. Inu ọdun yii ni mo de Ilọti.

Ohun to mu kawọn ọlọpaa mu mi ni pe mo fipa ba ọmọbinrin kan sun, ẹni to sun mọ mi si ni. Abule kan ti wọn n pe ni Ijẹbu Ilawẹ, ni mo kọkọ n gbe, amọ mi o laiki ibẹ, oun lo jẹ ki n ko wa si Ilọti, tori nigba ti mo wa ni Ilawẹ yẹn, mi o rẹni foju jọ, ko si ara ilu mi kankan nibẹ, amọ nigba ti mo de Ilọti, mo ri awọn ta a jọ jẹ ọmọ bibi Benue diẹ, iyẹn ni mo fi n gbe ni Ilọti yẹn.

Obinrin kan, Iya Agnes, araalu mi ni, oun ni iya ọmọbinrin ti mo fipa ba laṣẹpọ, a ti mọra daadaa nigba ti mo de Ilọti, ile wọn ni mo n lo si. Ile ọkọ niyaa Agnes wa o, Igede naa lọkọ ẹ, o si mọ mi. Amọ nigba to ya, ọkọ Iya Agnes ni oun ko fẹẹ ri mi nitosi iyawo oun, ki n ko jade, mo dẹ ko jade nile wọn.

Mi o mọdi to fi ni ki n kẹru mi lọsan-an kan oru kan o, amọ o da bii pe ọkunrin yẹn ati iyawo ẹ n ja, ọkọ ẹ ko si fẹ ki araalu ẹ kankan wa nitosi tabi ki wọn ba wọn da si i, o ṣaa ni ki n kẹru mi, mo si ṣe bẹẹ, mo lọọ rẹnti ile kan si Ijẹbu Odelẹwu. Mo sanwo oṣu mẹfa, mo n gbe ibẹ, amọ mo maa n jẹ si Ilọti daadaa, mo si maa n lọ sile awọn Iya Agnes yẹn, ibẹ naa ni mo ti maa n ṣere, to ba dalẹ ni mo n pada sile temi.

Nigba to ya, lilọ-bibọ yẹn fẹẹ su mi, tori irin yẹn nasẹ lojoojumọ, amọ nigba ti mi o ribi ṣere lọ, tori ẹ, mo pinnu lati kuku duro ni Ilọti ti mo ba ti pari iṣẹ oko ojumọ tan, ọwọ alẹ ni mo maa n pada sile.

‘‘Iṣẹ oko kan wa temi ati ẹnikan ta a n pe ni James gba, ọna Irawọ ni iṣẹ naa wa, a dako eweedu sibẹ, mo si maa n mu ewedu yii lọọ ta lọja.

Ni ọjọ tiṣẹlẹ yii waye, mo lọọ fẹ eweedu ti ma a ta lọja lọjọ keji ni, Iya Agnes ko si nile, o ti lọ si Ṣagamu lọọ yan gaari, o si dagbere fun mi nigba to n lọ. Nigba ti ọmọbinrin yẹn, Agnes, ati aburo ẹ tileewe de, o n dana ounjẹ ni kiṣinni wọn, aburo ẹ ati abikẹyin wọn si n ṣere ninu ile. Nigba to dana tan, o bu ounjẹ fun mi, mo jẹ ẹ, o si bu tawọn aburo ẹ naa fun wọn. Igba to ya lo ni ki n jẹ koun lọọ ba mi kiri eweedu, mo ni ko buru.

‘‘Mo sare di eweedu yẹn si keekeeke ba a ṣe maa n di i. Aburo Agnes loun o lọ ni toun o, mo dẹ ni mi o ni i fun un lowo ti awọn yooku ẹ ba de o. Emi o mọ pe ẹmi buruku ti n wọnu mi nigba yẹn. Eweedu yooku to ṣẹku ni mo lọọ ko si itosi baluwẹ wọn, ki oorun ma baa jẹ ko rọ, ki n le ta a lọjọ keji. Bi mo ṣe fẹẹ wọle pada, Agnes tẹle mi, o dẹ ti maa n fọwọ jẹ mi lara tẹlẹ, to maa n ba mi ṣere, o maa n rin mi ni kàké, bẹẹ ni mo n sọ fun un pe iwọ ọmọ yii, ki lo n wa, ki lo n wa? Tori o ti ṣẹlẹ nigba kan ti awọn kan lọọ sọ fun iya ẹ pe mo fẹẹ ba ọmọ ẹ laṣepọ, iya yẹn si gbe ọrọ yẹn sọkan, o fi huwa si mi bii ọjọ meji mẹta kan, ti mo n ki i, ti ki i da mi lohun daadaa.

‘‘Lọjọ yẹn ṣa, Agnes tẹle mi wọle, o ko bata ẹ to ti ja lọwọ, o n wa okun to fẹẹ fi so o, emi lọọ pọn omi nile keji pe ki n fi wọn eweedu mi to wa lẹhinkule nitosi baluwẹ wọn, bẹẹ lọmọbinrin yii ti mi, emi naa ti i, niṣe lo kan yọdi sẹyin si mi bi mo ṣe ti i, mo ni ki lo n fẹ to fi tẹle mi, o ni ewo lo kan mi. Mo ṣaa fa a dide, amọ ko dide, mo sọ fun un pe iwọ ọmọ yii, ma ko ba mi o, ma ko mi si wahala o, amọ ko dahun, ni mo ba bọ sikẹẹti ẹ, ko sọrọ, mo tun bọ pata ẹ, ko wi nnkan kan. Ibẹ ṣaa ni mo ti ba a laṣepọ. Gbogbo bi mo si ṣe n ba a sun, ko pariwo, ko sọrọ. Amọ ba a ṣe n ṣe ‘kinni’ lọwọ ni aburo ẹ wọle, bo ṣe gburoo ẹsẹ aburo ẹ lo bẹ dide, emi naa sare wọ ṣokoto mi. O sare lọọ duro saarin ọdẹ, emi naa si dọgbọn sa pamọ sinu baluwẹ.

 

‘‘Amọ bi aburo ẹ ṣe pada lọ sọdọ aunti ẹ lo ṣakiyesi pe ẹjẹ n jade lati abẹ ẹ, o ṣan wa sibi ẹsẹ ẹ, Agnes n dọgbọn pe ko ma ri i, amọ o ri i, lo ba pariwo sita pe awọn araadugbo, ibẹ lero ti pe le wa lori, wọn wọ mi lọ sọdọ baalẹ, ibẹ si ni wọn ti lọọ fọlọpaa mu mi nigba ti baba ọmọ yẹn de. Awọn ọlọpaa teṣan Igbẹba ni wọn mu mi, ọjọ mẹrin ni mo lo nibẹ ki wọn too wọn mi sọkọ wa si Eleweẹran.

Ẹjẹ to jade nidii ọmọ yẹn, o da bii pe o n ṣe nnkan oṣu lọwọ ni, o n ṣe nnkan oṣu lasiko ti mo fipa ba a sun. Ẹẹkan ṣoṣo pere naa ni mo ba a laṣẹpọ. Awọn obi ẹ ti waa wo mi ni teṣan, niṣe ni wọn n ṣepe fun mi, wọn binu si mi.

Mo kabaamọ ohun ti mo ṣe yii o, mo kabaamọ gidi ni, tori mi o ṣe iru nnkan bayii ri laye mi, loootọ mo ti ba obinrin sun ri o, amọ igba akọkọ ti mo ṣe e, obinrin yẹn gan-an lo reepu mi, oun lo fipa mu mi ṣe e.

Lati ikoko ni mama mi ti gbe mi kuro lọdọ baba mi, ti wọn kọra wọn silẹ. Mi o mọ ibi ti baba mi wa latigba naa, amọ iya mi wa ni Benue, labule wa. Mi o mọ boya o ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si mi yii o.

Ẹbẹ mi si ijọba ni pe ki wọn ṣaaanu mi, mi o ni i ṣeru ẹ mọ, ki wọn fori jin mi. Mo kabaamọ o.

Leave a Reply