Gbese ree o, maaluu bii aadọta jẹ majele, ni wọn ba ku danu n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Tẹkun-tomije lawọn ontaja kan ti wọn n ta maaluu ninu ọja Mandate, Adewọle, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, wa bayii, pẹlu bii maaluu wọn to le ni ogoji ṣe ku lojiji latari majele ti wọn jẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe awọn ontaja ọhun ni wọn lọọ fi awọn maaluu wọn jẹko lati inu ọja Mandate, lọ si inu ọgba ileewe College of Arabic and Legal Studies, to wa ni agbegbe naa, ṣugbọn nigba ti wọn n dari pada bọ wale nirọlẹ ni awọn maaluu ọhun bẹrẹ si i wo lulẹ, ti wọn si n ku eyi to mu ki maaluu to le ni ogoji ku loju-ẹṣẹ, ti wọn si n sọ ọbẹ si wọn lọrun.

Ọkan lara awọn to n taja ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Olugbọn, to ba oniroyin ṣọrọ ṣalaye pe lasiko tawọn maaluu naa n dari bọ lati ibi ti wọn ti lọọ jẹ koriko ni wọn n ṣubu lulẹ latari pe wọn jẹ majele mọ ounjẹ ti wọn jẹ, o ni ọkẹ aimọye miliọnu lawọn ti padanu bayii ṣibi iṣẹlẹ buruku naa.

Olugbọn, ti waa rawọ ẹbẹ sijọba Kwara atawọn ẹlẹyinju aanu pe ki wọn ran awọn lọwọ lori adanu naa, nitori pe gbese nla lo wọle tọ awọn lasiko ti eto ọrọ-aje dẹnu kọlẹ, ti gbogbo nnkan ko si jọra wọn tẹlẹ, aforiti lawọn n ṣe.

Babalọja inu ọja naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iṣẹlẹ ibanujẹ niṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo awọn to n ta maaluu ninu ọja, wọn waa rọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrasaq, ko dide iranwọ fun awọn tọrọ kan.

Leave a Reply