Oṣu kẹta ree ti NDLEA ti n wa awọn ogbologboo oniṣowo egboogi oloro tọwọ ba yii

Faith Adebọla

 Lẹyin oṣu meji tawọn ẹṣọ NDLEA ti n wa awọn afurasi ọdaran mẹta kan to jẹ pe ogbologboo ni wọn ninu okoowo egboogi oloro ṣiṣe, ọwọ ofin ti tẹ wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, awọn mẹtẹẹta si ti n ṣẹju pako lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n ṣalaye ẹnu wọn bayii.

Orukọ awọn afurasi naa ni Onyinyechi Irene Igbokwuputa. Abilekọ ni, ibuba kan to fori pamọ si niluu Eko, ni wọn ti fin in jade bii okete, ti wọn si mu un, bẹẹ lọwọ tun tẹ ẹni keji, Ọgbẹni Osita Emmanuel Obinna, Eko ni wọn ti mu oun naa, amọ ni ti ẹni kẹta wọn, Frankline Uzochukwu, oun ti sa lọ siluu Awka, nipinlẹ Anambra, ibẹ si lọwọ ti tẹ ẹ.

Oludari eto iroyin fun ajọ to n gbogun ti okoowo ati ilo egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, sọ ninu atẹjade ọlọsọọsẹ kan to fi ṣọwọ sori ikanni ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin yii pe latigba tawọn ti ri obitibiti egboogi oloro ti wọn n pe ni Heroine, ti aropọ rẹ tẹwọn to kilogiraamu mejilelaaadọta (51.90kg) gba lọwọ awọn kọlọransi ẹda kan lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko ti wọn fẹẹ gbe kinni naa sọda soke okun, lawọn ti bẹrẹ iwadii ijinlẹ nipa okooowo buruku ti wọn n ṣe, tawọn si ti n wa awọn afurasi tọwọ ṣẹṣẹ ba yii, tori niṣe ni wọn sa lọ rau nigba naa.

Babafẹmi ni kaakiri awọn orileede agbaye bii South Africa, Mozambique, Europe ati Amẹrika, titi kan Naijiria wa lawọn afurasi arufin yii ti ni ikọ to n ṣiṣẹ pẹlu wọn lati ṣe ataretare awọn egboogi tijọba ti fofin de ọhun.

Wọn ni aaye kan ti wọn ti n yẹ awọn ẹru wo ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed International Airport, to wa niluu Ikẹja, iyẹn SAHCO Import Shed, laṣiiri egboogi oloro rẹpẹtẹ ti wọn ko wọlu, eyi ti wọn dọgbọn fi pamọ sinu awọn ẹrọ ti wọn fi n ge irin, 2300-watt metal cutting machines, ti tu, tawọn si ti n wa wọn.

NDLEA ni awọn ti gba aṣẹ ile-ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn dukia bii ile, mọto atawọn nnkan meremere ti wọn ba fidi rẹ mulẹ pe o jẹ ti awọn afurasi wọnyi, tabi to jẹ owo ti wọn pa nidii okoowo ti ko bofin mu yii ni wọn fi ra a.

Babafẹmi ni ni bayii tọwọ ti tẹ awọn to sa lọ yii, awọn maa pari iwadii wọn ni koyakoya, tawọn yoo si tete taari wọn siwaju adajọ, ki wọn le lọ gbọ ohun tiwee ofin ilẹ wa sọ nipa ẹni to ba n ṣowo tijọba o fọwọ si fun wọn.

Leave a Reply