Agboọla Ajayi ti ẹgbẹ PDP ni yoo koju Ayedatiwa ninu ibo gomina Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbekeji Gomina ipinlẹ Ondo ni saa kin-in-ni Oloogbe Rotimi Akeredolu, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lo wọle ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti wọn di l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Alaga igbimọ ẹlẹni meje to ṣeto idibo ọhun, Ọgbẹni Lawrence Ewhrudjakpo, lo kede Ajayi lẹyin to fẹyin awọn oludije mẹfa yooku balẹ pẹlu ibo ọtalenigba le mẹrin (264) ti oun nikan ni.

Lati bii aago mẹjọ aarọ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ naa ti pejọ si gbọngan aṣa igbalode Doomu, to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti ṣeto ati yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu eto idibo gomina to n bọ.

Awọn to wa lati ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ondo nikan ni ẹgbẹ PDP naa faaye gba lati kopa ninu eto idibo abẹle ọhun.

Awọn meje ti wọn gba fọọmu lati dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP ni: igbakeji gomina tẹlẹ ri, Ọnarebu Agboọla Ajayi, kọmiṣanna fọrọ ayika lasiko iṣejọba Dokita Oluṣẹgun Mimiko, Oloye Oluṣọla Ẹbiṣeni, kọmiṣanna fọrọ ifi-to-ni-leti ninu ijọba Oloogbe Oluṣẹgun Agagu, John Máfọ̀, ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja fun ẹkun Ẹsẹ-Odo ati Ilajẹ nigba kan, Ọnarebu Kọlade Akinjọ, Bamidele Akingboye, Akinwumi Harrison ati Bọsun Arebuwa.

Ilana ṣiṣe amulo awọn aṣoju, (indirect primary) lẹgbẹ PDP fi ṣeto idibo abẹle tiwọn. Awọn dẹligeeti bii okoolelẹgbẹta le meje (627) ni wọn lo lati yan oludije to ba wu wọn ninu eto idibo abẹle naa.

Ninu atẹjade ti Alukoro ẹgbẹ oṣelu ọhun, Kennedy Ikantu Peretei, fi sita ki eto idibo yii too waye, o ni igbimọ ẹlẹni meje ti Igbakeji Gomina ipinlẹ Bayelsa, Lawrence Ewhrudjakpo jẹ alaga fun lawọn aṣaaju ẹgbẹ lorilẹ-ede yii yan lati ṣeto idibo naa.

Nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni wọn bẹrẹ pẹlu iforukọsilẹ ati ṣiṣe ayẹwo finni fawọn dẹligeeti to fẹẹ kopa.

Nigba to n b’awọn oniroyin sọrọ lasiko ti wọn bẹrẹ eto idibo ọhun, Ewhrudjakpo ni

adehun awọn ni pe gbogbo awọn oludije gbọdọ gba kamu, ki wọn si ṣe atilẹyin fun ẹnikẹni to ba yege lẹyin eto naa, ko baa le ṣee ṣe fun ẹgbẹ PDP lati rọwọ mu ninu eto idibo gomina to n bọ lọna ninu oṣu Kejila.

Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i pe awọn aṣoju naa wọle lati ijọba ibilẹ kọọkan, ijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko ni wọn ti bẹrẹ ni nnkan bii aago mẹrin ku isẹju mejila pẹlu awọn dẹligeeti mọkandinlogoji to fẹẹ dibo.

Awọn mọkanlelọgbọn lati Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, mẹrinlelogoji ni ti Guusu Ila-Oorun Akoko,  awọn mẹtalelogoji ni wọn dibo lati ijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, mẹtadinlogoji nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ ti ti Guusu Akurẹ si jẹ mẹrinlelọgbọn.

Agboọla Ajayi lo ṣaaju awọn mọkanlelọgbọn ti wọn dibo lati ijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, awọn dẹligeeti mọkanlelọgbọn ni ti Idanre, awọn mẹtadinlogoji lati ijọba ibilẹ Ilajẹ, ọgbọn lati Ilẹ-Oluji /Oke-Igbo, Ijọba ibilẹ Irele, mọkanlelọgbọn, Okitipupa, mọkandinlogoji, Ila-Oorun Ondo, mọkanlelọgbọn, Iwọ-Oorun Ondo, mẹtadinlogoji, Ọ̀sẹ́, mẹtadinlogoji pẹlu ijọba ibilẹ Ọwọ nibi tawọn aṣoju mẹrinlelọgbọn ti dibo.

Aago marun-un ku bii isẹju marun-un geere ni wọn pari ibo didi, apapọ iye awọn aṣoju to dibo jẹ okoolelẹgbẹta le ẹyọ kan, loju-ẹsẹ ni wọn si ti bẹrẹ kika ibo.

Ọnarebu Agboọla Ajayi lo ṣe ipo kin-in-ni pẹlu ibo ọtalenigba le mẹrin (264), Akinjọ Kọlade Victor to ni ibo mẹtadinlọgọjọ (157) gba ipo keji, Oluṣọla Ẹbiṣeni to ni ibo mọkandinlọgọrun-un ṣe ipo kẹta, Akinwumi Harrison lo ṣe ipo kẹrin pẹlu ibo mẹrinlelọgọta to ni, Akingboye Bamidele to ni ibo mẹrinlelogun wa nipo karun-un, ti Máfọ̀ John si ṣe ipo kẹfa pẹlu ibo mẹsan-an.

Nigba to n kede abajade eto idibo ọhun, Ewhrudjakpo ni awọn dẹligeeti okoolelẹgbẹta le ẹyọ kan ni wọn dibo, iyẹn awọn mẹta mẹta lati wọọdu kọọkan, ibo meji lo ṣofo, leyii to to mu ki gbogbo ibo to wọle jẹ mọkanlelẹgbẹta.

Niwọn igba to ti jẹ Ajayi lo ni ibo to pọ ju lọ, o ni oun nawọ rẹ soke gẹge bii ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ PDP ninu eto idibo gomina ipinlẹ Ondo ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii.

Ajayi dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ atawọn to ṣeto idibo naa fun akoyawọ wọn lati ibẹrẹ de opin.

O waa rọ gbogbo awọn ti wọn jọ dije lati fọwọsowọpọ pẹlu oun, ki ẹgbẹ PDP le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọna.

Leave a Reply