Ọwọ ọlọpaa tẹ akẹkọọ poli pẹlu fọọmu igbani-wọle sinu ẹgbẹ okunkun n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fọwo ofin mu akẹkọọ ileewe gbogbonise ijọba apapọ to wa niluu Bida, nipinlẹ Niger, (Federal Polytechnic Bida), pẹlu bi wọn ṣe ba fọọmu igbani wọle sinu ẹgbẹ okunkun lọwọ rẹ ninu otẹẹli kan niluu Ilọrin.

ALAROYE, gbọ pe latigba tawọn ọlọpaa ti n dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n rẹ ara wọn danu bii ila niluu Ilọrin, lati bii ọjọ diẹ ṣẹyin, ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun mejidinlọgbọn (30), ti wọn si ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ, ko too di pe ọwọ tun tẹ akẹkọọ to n pin fọọmu igbani-wọle ninu otẹẹli kan.

Kọmiṣanna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Victor Ọlaiya, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, sọ pe owuyẹ kan lo waa ta awọn lolobo pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun fara pamọ si otẹẹli kan niluu Ilọrin, tawọn ọlọpaa si lọọ ko wọn, “Awọn akẹkọọ mẹfa ti wọn wa lati ileewe gbogbonise ijọba apapọ tilu Bida, nipinlẹ Niger, lọwọ tun tẹ bayii.

Ọlaiya ni akẹkọọ ti wọn ba fọọmu igbani-wọle lọwọ rẹ jẹwọ pe loootọ ọmọ ẹgbẹ okunkun loun, ati pe awọn waa ṣepade ni otẹẹli naa lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle ni.

Ọlaiya ni laipẹ lawọn yoo foju awọn afurasi naa bale-ẹjọ.

Leave a Reply