Ahmed Musa, agbabọọlu ilẹ wa, fẹyawo keji

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Agbami ifẹ ẹlẹẹkeji ni agbabọọlu ilẹ wa nni, Ahmed Musa, ti n luwẹẹ bayii, pẹlu bo ṣe ṣẹṣẹ ṣegbeyawo pẹlu arẹwa obinrin kan to wa lati ẹya Shuwa Arab. Mariam lorukọ orekẹlẹwa ti Musa fẹ ni bọnkẹlẹ yii, wọn ko pariwo igbeyawo naa rara.

Igbeyawo yii waye lẹyin ọdun mẹrin ti Ahmed Musa fẹ Juliet Ejue, ọmọ ilu Ogoja, nipinlẹ Cross-River. Ọmọ meji ni Juliet bi fun agbabọọlu yii, wọn si jọ wa titi dasiko yii ti ọkunrin naa fẹyawo tuntun ni.

Tẹ o ba gbagbe, obinrin Hausa kan to n jẹ Jamila ni agbabọọlu Leicester City yii kọkọ fẹ, obinrin naa bimọ meji fun un ki igbeyawo ọhun too daru lọdun 2017.

Leave a Reply