Iwa tawọn tawọn DSS hu si Sunday Igboho le ṣakoba fun iṣọkan orilẹ-ede Naijiria-Awọn ọba Yoruba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ajọ awọn lọbalọba ilẹ Yoruba ti koro oju si bi ijọba apapọ ṣe kọ lu ile Oloye Suday Adeyẹmọ (Igboho) lọsẹ to kọja lọhun-un, wọn ni bi wọn ṣe paayan meji nile rẹ ti wọn tun ba ọpọlọpọ dukia jẹ ko boju mu rara.

Ipade kan tawọn ọba naa ṣe ni wọn ti sọ ọrọ yii, atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọba Ọmọwe Samuel Adeoye (Molokun Ajitere,Ilajẹ nipinlẹ Ondo), ati Olukọtun Ikọtun-ile ni Kwara, Ọba Ọmọwe Abdulrasaq Abioye, fọwọ si ni wọn fi ṣalaye pe ohun tawọn DSS rọra dan wo naa le ṣakoba fun iṣọkan orilẹ-ede Naijiria bi wọn ko ba fi ọwọ to yẹ mu un.

Awọn kabiyesi yii sọ pe ko si idi kan fawọn DSS to paayan nile Igboho lati ṣe bẹẹ, wọn ni titẹ ẹtọ ọmọlakeji loju mọlẹ ni, iwa ipa si ni pẹlu. Fun ohun ti wọn ṣe yii, awọn ọba alaye naa ke pe ijọba Buhari lati tete fi awọn ẹni ẹlẹni ti wọn ko satimọle nile Igboho silẹ, bẹẹ ni wọn ni kijọba apapọ ṣeto gba-ma-binu fawọn meji ti wọn ku iku ojiji ninu ikọlu ti wọn ṣe sile Igboho lọjọ kin-in-ni oṣu keje yii.

Ko tan sibẹ, awọn Kabiyesi tun sọ pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ pe ki iwadii to lagbara waye lori ikọlu naa, ki otitọ ibẹ lo foju han kedere.

Lori ipo ti eto aabo wa lorilẹ-ede yii bayii, awọn lọbalọba naa sọ pe ohun ti ko ṣee duro wo mọ rara ni, nitori o ti doju ẹ patapata. Wọn ni bo ṣe n daamu ọkan awọn gẹgẹ bii ọba naa lo n ri lara awọn ọmọ Naijiria gbogbo.

Wọn ṣalaye nipa ijinigbe to n ṣẹlẹ nilẹ Hausa, ipaniyan to n ṣẹlẹ nibẹ ati ija ẹlẹyamẹya to tun n ṣẹlẹ lawọn apa kan orilẹ-ede yii.

Awọn oriade to pe jọ yii dupẹ lọwọ awọn gomina ilẹ Yoruba to gbe Amọtẹkun kalẹ lati jagun aabo, wọn ni idasilẹ ikọ naa n ran aabo araalu lọwọ.

Diẹ ninu awọn ọba to wa nibi ipade naa ni Ẹlẹrinmọ ti Ẹrinmọ Ijẹṣa, Ọba Ọmọwe Micheal Ajayi, Alagbado ti Agbado, nipinlẹ Ogun; Ọba Adedayọ Ṣogbulu, Ọba Aderibigbe Asunmọ ti Odo Ayandelu, nipinlẹ Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply