Aja yii ko ro rere kan Ọpẹyẹmi o, ‘kinni’ ẹ lo ge jẹ l’Akungba-Akoko

Faith Adebọla

Orukọ lo ro akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin ti wọn pe ni Ọpẹyẹmi Sadiq yii o, tori orin ọpẹ lo maa wa lẹnu ọmọ ọdun mejidinlogun naa, latari ori to ko o yọ lọwọ aja digbolugi kan to ge e jẹ labẹ, diẹ lo ku ki ‘kinni’ ẹ lọ si i.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye laarin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii ninu ọgba ileewe fasiti ọhun. Ọpẹyẹmi ni koun ṣere lọọ ki ọrẹ oun nile rẹ, Vanilla Villa, laaarọ ọjọ naa ni. Wọn ni bo ṣe ku diẹ ko wọ ile to n lọ naa ni aja ti wọn porukọ ẹ ni Chalie yii pakuuru mọ ọn, to si gbe e wọnlẹ, lo ba feyin bu ṣokoto rẹ so.

Nibi t’Ọpẹyẹmi ti n lọgun, to si n sapa lati gba ara ẹ lọwọ aja ọhun ni aja ti bu u jẹ, oke itan rẹ laja naa ge jẹ, eyin aja naa si kan nnkan ọmọkunrin rẹ fẹẹrẹfẹ.

A gbọ pe awọn eeyan to n kiyesi ohun to n ṣẹlẹ lọọọkan, atawọn to sare jade nigba ti wọn gbọ ariwo rẹ ati bi aja ọhun ṣe n gbo, ni wọn waa gba a silẹ, ti wọn si le aja ọhun sẹyin.

Alukoro ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti ọhun, Oluwafẹmi Adegbeyeni, sọ fun iweeroyin Punch pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe wọn gbe Ọpẹyẹmi lọ sileewosan kan, Inland Specialist Hospital, n’Ikarẹ, ipinlẹ Ondo, nibi to ti n gba itọju pajawiri lọwọ.

O  ni eyin aja naa ba nnkan ọmọkunrin ẹ, ṣugbọn ko ṣee leṣe ju, o si ti n gbadun diẹdiẹ.

Oluwafẹmi tun fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa ti gbe mọto wọn wa, wọn si ti fi gbe aja digbolugi naa lọ.

Wọn ni akẹkọọ ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Abass Ọlagunju, lo ni Chalie, aja naa si ṣẹṣẹ pe ọdun meji aabọ ni, ati pe lati bii ọjọ diẹ sẹyin ni iṣesi aja ọhun ti yatọ, latari bo ṣe n gbo, to si n ṣẹru ba awọn eeyan to n kọja laduugbo naa.

Wọn ni imọ nipa awọn ẹranko ni Abass n kẹkọọ rẹ, o si ti wa nipele aṣekagba nileewe naa.

Leave a Reply