Ajagungbalẹ mẹta ko sọwọ ọlọpaa l’Odogbolu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi awọn ọkunrin yii ṣe ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa, lẹka itọpinpin, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn yooku wọn ti wọn jọ ya wọ ori ilẹ kan ti iṣẹ ile ti n lọ lọwọ l’Odogbolu, nipinlẹ Ogun, iyẹn lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa yii, nibi ti wọn ti le awọn to n ṣiṣẹ lori ilẹ naa danu, ti wọn si gba idaji miliọnu naira ati foonu ologoji ẹgbẹrun lọwọ obinrin kan, Kẹmi Olukọya.

Olukọya yii lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Odogbolu, pe awọn ajagungbalẹ kan ya wọ ori ilẹ tawọn eeyan oun ti n ṣiṣẹ lọwọ, toun gẹgẹ bii alamoojuto si n mojuto wọn.

O ni awọn ajagungbalẹ naa to mẹjọ, tibọn-tibọn ni wọn si wa, to jẹ niṣe ni wọn bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ titi tawọn to n ṣiṣẹ fi sa lọ.

Kẹmi sọ fawọn ọlọpaa pe baagi toun gbe dani, eyi ti idaji miliọnu naira wa ninu ẹ lawọn ajagungbalẹ naa gba, ti wọn tun gba foonu lọwọ oun loju ibọn, ẹgbẹrun lọna ogoji naira lo pe owo foonu naa.

O ni wọn ti pitu ọhun tan loun ṣe waa fẹjọ sun.

DPO Odogbolu, SP Adeniyi Awokunle, ko awọn ikọ rẹ lọ si saiti naa, wọn si ba ninu awọn ajagunbalẹ naa ti wọn n wa ọna lati sa lọ.

Awọn ọlọpaa le wọn, wọn si ri Wasiu Adenuga, Micheal John ati Mọruf Alaba mu. Bẹẹ naa ni wọn ri ọkada Bajaj wọn naa pẹlu, awọn ọlọpaa si ko gbogbo wọn, o di teṣan.

Wọn pe Kẹmi ko waa wo wọn wo boya awọn ti wọn ya bo oko rẹ ni, obinrin naa si ni bẹẹ ni. O ni mẹta ree ninu awọn bii mẹjọ to ya wọ saiti naa tibọn-tibọn.

Eyi lo mu CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn ko awọn mẹta yii lọ sẹka ti wọn yoo ti fọrọ wa wọn lẹnu wo si i, ti wọn yoo fi mọ awọn yooku wọn pẹlu, ti wọn yoo si mu wọn ṣinkun.

Leave a Reply