Ajọ eleto idbo ti bẹrẹ si i ko esi idibo sori ẹrọ alatagba wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ajọ eleto idibo ti ṣe agbekalẹ ẹrọ alatagba kan ti wọn n pe ni (server), ti wọn yoo ko gbogbo esi idibo to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, si. Nibẹ ni wọn yoo si ti pada maa kede rẹ nigba ti wọn ba pari akojọpọ naa tan.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti gbogbo eto didi ati kika ibo ti pari kaakiri awọn ijọba ibilẹ ti eto idibo naa ti waye nipinlẹ Ọṣun.

Lati bii aago marun-un kọja diẹ ti awọn esi idibo yii ti n wọle lalẹ ọjọ Abamẹta yii ni wọn bẹrẹ si i ko wọn jọ sori ẹrọ ti wọn pe ni server yii gẹgẹ bi Ajọ Akoroyin jọ ilẹ wa ṣe sọ.

Ọpọlọpọ awọn esi idibo lati awọn wọọdu lawọn ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti n ko sori ẹrọ alatagba yii.

Lẹyin ti wọn ba ko gbogbo rẹ sibẹ tan ti aropọ ati ayọkuro waye ni wọn yoo ṣẹṣẹ too kede esi idibo ọhun.

Ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ni wọn ṣe agbekalẹ ibi ti wọn yoo ti maa gba awọn esi idibo to ba ti de yii sori ẹrọ alatagba wọn si, nibẹ naa ni wọn yoo si ti pada kede rẹ lẹyin ti wọn ba pari iko sinu ẹrọ yii tan.

Leave a Reply