Ajọ eleto idibo fagi le owo idije awọn alaga ati kansilọ l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

OGSIEC, iyẹn ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun ti fagi le owo idije ti wọn ni awọn oludije sipo alaga ati kansilọ yoo san ki wọn too le dupo tẹlẹ, wọn ni ọfẹ ni fọọmu bayii.

Ṣe latilẹ ni ajọ naa ti Ọgbẹni Babatunde Osibodu n ṣe alaga ẹ nipinlẹ yii ti kede pe ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) lẹni to ba fẹẹ dupo alaga ibilẹ yoo san, ti awọn to fẹẹ di kansilọ yoo si gba fọọmu tiwọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000).

Ṣugbọn lopin ọsẹ to kọja, Alaga OGSIEC kede pe awọn ko ni i gbowo kankan lọwọ awọn oludije mọ, ọfẹ ni.

Lori idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii, Osibodu ṣalaye pe idajọ ile-ẹjọ kan to waye loṣu karun-un, ọdun 2014, ti Adajọ G.O Ṣorẹmi da lo fofin de gbigba owo fọọmu.

O ni nigba tawọn si ti ri ẹri to fidi ẹ mulẹ lati kootu, idi niyẹn to fi di dandan lati mu ẹnu kuro ninu ọrọ owo fawọn oludije.

O tẹsiwaju pe OGSIEC ko wulẹ ti i gbowo kankan lọwọ awọn oludije tẹlẹ, nitori naa, ko si ọrọ a n dawo pada fun ẹnikẹni.

Ohun to ku bayii gẹgẹ bo ṣe wi ko ju kawọn ti wọn ko ba ti i gba fọọmu tete lọọ gba a l’Oke-Ilewo, lọfiisi ajọ eleto idibo.

Bakan naa lo ni awọn ti bẹrẹ si i fi orukọ awọn oludije ti wọn ti yanju eto tiwọn ranṣẹ sawọn ẹgbẹ oṣelu to fa ọmọ oye kalẹ fun idibo ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje ọdun 2021 yii.

Leave a Reply