Akẹkọọ ti wọn pa ni Sokoto: Mr Macaroni sọko ọrọ si Atiku

Monisọla Saka
Ọkan ninu awọn gbajumọ adẹrin-in pṣonu ile wa, Adebọwale Adedayọ ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni, ti sọko ọrọ si igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Atiku Abubakar, fun pipa to pa ohun to kọ rẹ, nibi to ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu awọn apaayan ti wọn pa ọmọlẹyin Krisiti nni, Deborah Samuel, tawọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ pa lori ọrọ ẹsin.
Ọkunrin ẹlẹfẹ ori ẹrọ ayelujara ọhun ta ko iwa ipaniyan ọhun. O ṣalaye pe yiyọ ti Atiku yọ ọrọ to kọ lodi si iwa laabi ọhun lori ẹrọ abẹyẹfo rẹ fi han pe ohun to jẹ ẹ logun ni ipo agbara to fẹẹ di mu ju igbaye-gbadun awọn araalu.
Ninu ọrọ Mr. Macaroni lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ, o ni, “Ohun to mu ki Atiku ko ọrọ to sọ jẹ tumọ si pe iwaasu lasan la n ṣe lati ọjọ yii lori ọrọ eto idibo.
Awọn oloṣelu o ri tawọn eeyan ro. Wọn kan maa n ṣe oju aye tasiko ibo ba ti to ni. O yẹ kawọn eeyan laju ki wọn si rina kọja gbogbo ẹtan wọn yii.
“Gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ni wọn lẹtọọ lati gbele aye lai si ibẹru ẹnikẹni. Ẹnikẹni tabi apapọ eeyan kankan o lẹtọọ lati gbẹmi eeyan ẹgbẹ ẹ nilẹ yii.
O tẹsiwaju pe, “O o le pa ọmọlakeji ẹ nitori pe o n gbeja ẹsin kankan. Ṣe ki gbogbo wa waa maa para wa lori ọrọ ẹsin ni? Iwa ọdaju gbaa ni.

Ninu ọrọ Atiku Abubakar, o ni, “Ko si awijare fun iwa ọdaju ati iru ipaniyan bẹẹ. Wọn pa Deborah Samuel, gbogbo awọn ti wọn si pa a ni wọn yoo dajọ to tọ fun wọn.’’
Ko pẹ lẹyin eyi ni igbakeji aarẹ tẹlẹ ọhun, sare yọ ohun to kọ sori ẹrọ ayelujara kuro latari didun ti awọn ẹlẹsin Musulumi nilẹ Hausa dunkooko mọ ọn pe awọn o ni i dibo fun un lati wọle aarẹ to ba fi le jawe olubori ninu ibo abẹle ẹgbẹ PDP to ti sun mọle tan yii.
Wọn tun ṣeleri pe awọn yoo kora jọ pọ ṣiṣẹ ta ko o ni.

Leave a Reply