Akeredolu gbe aba eto isuna ọdun to n bọ lọ siwaju awọn aṣofin

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti gbe owo to to ọrinlelugba din diẹ biliọnu Naira (#272.736b) siwaju awọn aṣofin ipinlẹ Ondo gẹ́gẹ́ bii owo aba eto isuna ọdun 2023 fun ibuwọlu wọn.

Ninu ọrọ ti gomina ọhun bawọn eeyan sọ lasiko to n tẹ pẹpẹ aba eto isuna naa lasiko ijokoo ile lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kejila yii, lo ti fi ye wọn pe owo tijọba oun n gbero ati na lọdun to n bọ fi diẹ gbe pẹẹli ju ti ti akoko yii lọ.

O ni biliọnu mẹtalelogoje aabọ Naira (#143. 511b) loun ya sọtọ ninu owo naa lati na lori awọn akanṣe iṣẹ tuntun, nigba ti biliọnu mọkandinlaaadoje ati diẹ to ku yoo wa fun pipari awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ilu to n lọ lọwọ.

Aketi ni owo ti oun gbe wa siwaju awọn aṣofin gẹgẹ bii owo aba eto isuna jẹ abajade ipade gbọngan ilu ti oun ti kọkọ ṣe kaakiri ipinlẹ Ondo pẹlu awọn ti ọrọ kan.

O ni bo tilẹ jẹ pe iwọnba owo perete lo n wọ asunwọn ijọba ipinlẹ Ondo, sibẹ ijọba oun ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe awọn iṣẹ idagbasoke ko dawọ duro rara labẹ bo ti wu ko mọ.

Ninu ọrọ Olori ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, nigba to n tẹwọ gba aba eto isuna ọhun, o ni igbesẹ titẹ pẹpẹ aba eto isuna lọdọọdun jẹ imuṣẹ ilana ofin Naijiria, nitori pe anfaani awọn araalu ni igbekalẹ rẹ wa fun.

O dupẹ lọwọ gomina fun gbogbo iṣẹ idagbasoke to n ṣe, paapaa fun bo ṣe ba wọn tun ile-igbimọ aṣofin ti wọn wa ṣe daadaa.

 

Leave a Reply