Akeredolu ki Tinubu ku oriire

Ọrẹoluwa Adedeji
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ki Aṣiwaju Bọla Tinubu ti ẹgbẹ APC ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii oludije wọn lati dupo aarẹ ku oriire.
Alaga awọn gomina APC nilẹ Yoruba naa sọ pe asiko niyi lati para pọ ni iṣọkan, kawọn si ri i pe awọn jawe olubori ninu eto idibo to n bọ yii.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlatunde, fi sita lorukọ gomina lo ti ni Akeredolu gboṣuba fun Tinubu pẹlu bi wọn ṣe yan an gẹgẹ bii ẹni ti yoo dijẹ dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn lọdun to n bọ. Bakan naa lo ki ẹgbẹ naa ku oriire fun bi eto idibo naa ṣe lọ nirọwọrọsẹ.
O fi kun un pe oludije naa pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC gbọdọ gbaruku ti ẹgbẹ yii, ki wọn si mu un duro giri lati mura silẹ fun aṣeyọri to ju eleyii lọ.
Akeredolu ni, ‘‘Iṣẹ to pọ ni o wa niwaju wa, a si ni lati gbagbe gbogbo ohun to ṣẹlẹ latẹyinwa, ki a gba alaafia, itẹsiwaju ati iṣọkan laaye ninu ẹgbẹ wa.
Bakan naa lo gboṣuba fun Aarẹ Buhari, awọn gomina iilẹ Hausa mẹtala ti wọn fohun ṣokan pe ki aarẹ wa lati iha Guusu, ati awọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.

Leave a Reply