Akeredolu siju aanu wo awọn ẹlẹwọn mọkanla fun ayajọ ọdun tuntun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti siju aanu wo awọn ẹlẹwọn mọkanla lati fi ṣami ayẹyẹ ayajọ ọdun tuntun ta a wa yii.

Mẹrin ninu awọn ẹlẹwọn ọhun ni wọn gba idariji patapata kuro lọgba ẹwọn, nigba ti gomina pasẹ yiyi idajọ iku ti wọn da fun awọn mẹfa pada si ẹwọn gbere.

Ẹlẹwọn kan to n ṣẹwọn gbere lọwọ ni gomina tun siju aanu wo, to si ni ki wọn yi i pada si ọdun mẹẹẹdogun.

Arakunrin ni igbesẹ ti oun gbe naa wa ni ibamu pẹlu abala igba le mejila (212) ninu iwe ofin orilẹ-ede yii ti ọdun 1999.

O ni oun ṣiju aanu wo awọn ẹlẹwọn ọhun latari iroyin rere ti oun n gbọ nipa wọn laarin asiko ti wọn fi wa lawọn ọgba atunṣe to wa nipinlẹ Ondo.

Gomina kilọ fawọn ti wọn ri idariji gba naa lati yago fun iwakiwa to tun le da wọn pada sọgba ẹwọn, bakan naa lo rọ awọn eeyan awujọ ki wọn fa wọn mọra, o ni ki wọn sọra lori iwa didẹyẹ si iru awọn eeyan bẹẹ.

 

Leave a Reply