Akinwale, Profẹsọ to n ṣere tiata, ku lojiji

Kazeem Ọlajide

Lojiji ni iroyin ọhun gba igboro lọwọ aṣaale ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti wọn gbọ pe Ọjọgbọn onimọ nla ninu iṣẹ sinima, Ayọbami Akinwale, ti ku.

ALAROYE gbọ pe aisan ranpẹ lo ṣe baba naa, nibi ti wọn si ti n ṣe itọju ẹ lọwọ ni ọlọjọ ti de, ti gbajumọ nla nidii iṣẹ tiata yii ko si le ba ara aye jẹun mọ.

Ileewe giga Yunifasiti ilu Ilọrin ni Ọjọgbon Ayọbami Akinwale ti n kọ awọn ọmọ lẹkọọ iṣẹ sinima ati ere ori-itage.

Yatọ si pe o jẹ olukọni agba, bakan naa lo tun maa n kopa daadaa ninu awọn fiimu Yoruba ati oyinbo, paapaa awọn sinima to n jade lati ileeṣẹ Main Frame ti Ọgbẹni Tunde Kilani atawọn fiimu mi-in.

Bi okiki iku ẹ yii ti ṣe gba igboro kan lawọn ẹlẹgbẹ ẹ nidii iṣẹ sinima ti n kẹdun ẹ gidigidi, bẹẹ lawọn akẹkọọ to ti kọ niwee ri paapaa naa ṣedaro olukọ nla yii.

Ninu ọrọ Ọga Bello, iyẹn Ọtunba Adebayọ Salami, lo ti sọ pe, “Ohun ikaya nla ni iku Ọjọgbọn Ayọ Akinwale jẹ fun mi nigba ti mo gbọ, ọga agba ni ti a ba n sọ nipa oṣere to laami-laaka, bẹẹ lo tun jẹ oludari ere to mọ iṣẹ ọhun debi gongo. Ti a ba tun n sọ nipa ẹni to le ṣe lameyitọ iṣẹ sinima daadaa, ọga ni ọ, bakan naa lo tun jẹ oludari pataki pẹlu. Eeyan nla ni ẹgbẹ oṣere sọnu yii, paapaa ẹka ẹgbẹ wa to wa niluu Ilọrin. Ki Ọlọrun rọ awọn ẹbi ẹ loju, ati gbogbo ẹgbẹ oṣere lapapọ.”

Ọkan lara awọn akẹkọọ ti oloogbe yii ti kọ ri, Ọgbẹni Tunde Olaoye, naa ko sai kẹdun iku Ọjọgbọn Ayọbami, bẹẹ lo ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii olukọ nla, to tun jẹ oṣere gidi pẹlu. Bakan naa lo sọ pe awokọṣe rere ni fun gbogbo eeyan to pade ẹ nigba to wa laye. O ni, “Aṣe wura nla ni awọn olukọ wa.”

Bi awọn eeyan ṣe n fi ẹdun ọkan wọn han ree, ti kaluku si n fidi ẹ mulẹ wi pe erin nla lo wo laarin awọn oṣere tiata ni Nigeria, ati pe Ọjọgbọn Akinwale yii, adanu nla ni iku ẹ jẹ laarin awọn oṣere gbogbo.

 

Leave a Reply