Ọlawale Ajao, Ibadan
Dandan ni ki iran Yoruba kuro lara orileede Naijiria, ki wọn si da duro gẹgẹ bii orileede kan laaye ara wọn. Eyi ni ipinnu agbarijọ ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye nibi ayẹyẹ ti wọn ṣe ni iranti adehun iṣọkan ti awọn adari ilẹ Yoruba ba ara wọn ṣe lọdun 1886, lẹyin ti Ogun Kiriji, iyẹn ogun abẹle ti wọn ba ara wọn ja fun ọgọrun-un ọdun gbako, pari tan.
Nile-ẹgbẹ Yoruba World Congress (YWC) to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan, leto ọhun ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, oni.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, aṣaaju ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye, Ọjogbọn Banji Akintoye, ṣeleri pe gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe Yoruba da duro laaye ara wọn gẹgẹ bii orileede kan.
O ni yatọ si pe oun ti gbe ọrọ naa lọ siwaju ajọ agbaye, pe awọn ọmọ Yoruba n fẹ ominira, ọpọlọpọ ìwọ́de lawọn ọmọ Oodua, paapaa nilẹ okeere, ti ṣe lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe asiko ti to fun awọn ọmọ Yoruba lati maa da ijọba ara wọn ṣe, ṣugbọn wọn ko ni i jẹ ki eyikeyii ninu ilakaka wọn ọhun la wahala tabi jagidijagan lọ.
Gẹgẹ bo ṣe kilọ fun gbogbo ọmọ Kaaarọ-o-o-ji-ire-bi lati ma ṣe ṣe iwọde ti yoo la wahala lọ lori ọrọ ominira ti wọn rawọ le yii, Ọjọgbọn Akintoye sọ pe “Tẹ ẹ ba fa wahala nibi kan, ti awọn eeyan ba le ku, ẹ n ṣakoba fun ilakaka wa lati gba ominira niyẹn. Ifikunlukun ati iwọde wọọrọ ti ko la wahala lọ la maa ṣe lati gba ominira fun ilẹ Yoruba.
“A ti ṣe iru iwọde alaafia bẹẹ lasiko ta a fẹẹ da ikọ eleto aabo ta a pe ni Amọtẹkun silẹ, wọn ko si mu ẹnikẹni nigba naa nitori a ko fa wahala. Ko si ẹni to gbọdọ ba nnkan jẹ nitori ọrọ ominira ta a fẹẹ gba yii. Ẹni to ba ba nnkan jẹ tabi to fa wahala, o n dina mọ ominira ta a fẹẹ gba ni.”
Ninu ọrọ tiẹ, Oloye Deji Ọṣibogun to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ redio Space FM ati ẹgbẹ Yoruba Kọya gba gbogbo ọmọ Yoruba niyanju lati ṣe ara wọn loṣuṣu ọwọ, ki wọn le wa ni iṣọkan lati doju kọ ọta to ba n dena igbaye-gbadun ati ilọsiwaju wọn.
Otun Olubadan tilẹ Ibadan, Agba-oye Lekan Balogun, ati Ọnarebu Tayọ Sarumi naa wa lara awọn olukopa nibi eto naa.
Bakan naa la ri awọn ạṣoju ẹgbẹ Yoruba loriṣiriṣi bii ẹgbẹ OPC, Kaaarọ-o-o-ji-ire Initiative, Yoruba Lagba, ẹgbẹ awọn fijilante, ẹgbẹ ọdọ Yoruba ti wọn n pe ni YYSA ati bẹẹ bẹẹ lọ.