Akọrin ẹmi nni, Sammie Okposo, ku lojiji

Lọla Ojo

Akọrin ẹmi to gbajumọ daadaa nni, Sammie Okposo, ti ku o.

ALAROYE gbọ pe ṣe ni ọkunrin naa ṣubu lulẹ lojiji laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, to si gbabẹ ku.

Ẹni ọdun mọkanlelaaadọta ni ọkunrin ti okiki rẹ kan pẹlu orin ẹmi kan ti wọn n pe ni ‘Wẹlu wẹlu’ to kọ, nitori ọdun to kọja lo ṣe ayẹyẹ ọjọọbi aadọta ọdun to dele aye.

Ko ti i ṣeni to le sọ ohun to ṣokunfa ohun to fa iku ọkunrin to ni ileesẹ Zamar Entertainment yii.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni ọkurin olorin ti wọn maa n pe kaakiri ileejọsin yii tọrọ aforiiji lọwọ iyawo rẹ nita gbangba, nitori awọn asemaṣe kan to ṣe pẹlu obinrin kan lorileede Amẹrika.

Leave a Reply