Ọlawale Ajao, Ibadan
Elewi ibilẹ kan lo sọ ninu orin ewi rẹ kan pe “Eeyan wọn, eeyan ṣoro, ara aye, eniyan ṣoro, ẹ bẹru eeyan. Ohun to ṣẹlẹ gan-an ree ni mọsalasi Ago-Ibira Central Mosque, to wa ni Mọkọla, ni’badan, nigba ti ẹni ti i ṣe akọwe mọsalasi nla ọhun, Abdulateef Jimoh, ẹni ọdun mẹrindinlaaadota (46), ati akapo ijọ Ọlọrun naa, Abdulrahman Jimoh, gbimọ–pọ lati lu mọṣalaasi naa ni jibiti owo to jẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta-o-le-marun-n Naira (N605,000).
Ile-ejo Majisireti to wa n’Iyaganku, niluu Ibadan, lawọn afurasi mejeeji ti wọn jẹ olugbe Agọ-Ibira, ti n kawọ pọnyin rojọ bayii lori ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.
Awọn ẹsun ti wọn ká sí wọn lẹsẹ ni kootu ọhun ni pe wọn lẹdi apo pọ lati huwa jibiti. Bẹẹ ni wọn já Ọlọrun lọle, wọn ji’wo ni mọṣalaaṣi.
Lọọya to jẹ agbẹjọro fun ijọba lori ẹsun naa, Amofin Gbemisọla Adedeji, sọ niwaju adajọ pe niṣe lawọn olujẹjọ meji yii gbimọ–pọ lati lu owo mọṣalaaṣi ni ponpo.
O ṣalaye pe awọn olujẹjọ ẹsun jibiti mejeeji wọnyi lawọn janmọ-ọn mọṣalaṣi nla to wa laduugbo Mọkọla, n’Ibadan yii, n ko tọrọ kọbọ ti wọn fi n ba Ọlọrun dowo pọ pamọ sí.
O ni lati ọdun 2018 lawọn olujọsin naa ti n da owo ọhun ni gbogbo ọjọ Jimọ Jimọ, bi wọn ba si ti pari isin tan, Abdullateef ati Abdulrahman ni wọn maa ko awọn owo naa fun lati maa tọju ẹ sileefowopamọ fun anfaani mọṣalaaṣi lọjọ iwaju
Gẹgẹ bi obinrin amofin to n jẹ Adedeji yii ṣe sọ, kaka ki awọn ẹru Ọlọrun wọnyi kowo si banki fun bukaata mọṣalaaṣi, apo ara wọn ni wọn n kowo pamọ si fun bukaata ara wọn.
Amọ ṣaa o, awọn mejeeji ti ṣalaye pe awọn ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun ti wọn ka si awọn lẹsẹ naa.
Agbejoro awon afurasi yii, Sunday Adediran, waa rọ ile-ẹjọ pe lati gba beeli wọn lai foju ọdaran wo wọn rara.
Adajọ kootu naa, Onidaajọ O.A. Akande, gbẹbẹ amofin naa, o si gba beeli ọkọọkan awọn olujẹjọ wọnyi pẹlu oniduuro meji ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000).