Akoko perete lo ku fun Naijiria, ori ọgẹgẹrẹ la wa bayii-Sanusi

Faith Adebọla

 Ẹmia ilu Kano ana, Sanusi Lamido Sanusi, Muhammadu Sanusi keji, ti ṣekilọ fawọn to n fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023 pe iṣẹ to wa nilẹ lati tun orileede yii ṣe pọ kọja bi wọn ṣe lero, tori ipo ti Naijiria wa ko dara rara, o lo buru ju ohun tawọn eeyan ati ijọba n sọ lọ, akoko perete lo ni o ṣẹku fun Naijiria ki gbogbo ẹ too tuka yanga.

Ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni Sanusi, to ti figba kan jẹ ọga agba banki apapọ ilẹ wa (Central Bank of Nigeria) ti sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu keji yii, nibi eto igbalejo ti wọn ṣe fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ọgọrin (80) ọdun Babanla Adinni tilẹ Ẹgba, Oloye Tayọ Ṣowunmi.

Sanusi ni afi bi awọn eeyan ba jẹ ki wọn tan wọn jẹ lo ku, wahala ati akoko lile koko tawọn ọmọ Naijiria maa koju lati asiko yii lọ di ọdun 2023 yoo pọ si i ju tatẹyinwa lọ.

O ni: “Ni tododo, asiko perete lo ṣẹku, ọgẹgẹrẹ la si wa. Lọdun 2015, inu koto jinjin la wa, niṣe ni koto naa n jin si i, to ba fi maa di ọdun 2023, aa ti jin gidi ju ti 2015 lọ.

“Mi o ro pe awọn ti wọn n lakaka lati dupo aarẹ yii mọ bi iṣoro ti wọn fẹẹ koju rẹ ṣe ti pọ ju tọdun 2015 lọ ni ilọpo ilọpo to. Afi ki gbogbo waa lọọ gbaradi de awọn ipinnu to le koko, ka si mọ pe a jọọ maa fara da a ni.

“Ki i ṣe pe ki gbogbo wa bẹ sinu oṣelu lo le yanju ọrọ ilẹ yii o, orileede yii nilo awọn oloṣelu rere, awọn Imaamu, Pasitọ ati Biṣọọbu to le duro lori ootọ, ti wọn aa le ran awọn oloṣelu leti pe ki wọn bẹru Ọlọrun.

“O tun nilo awọn ọjafafa ọmọwe ati oniriiri, ti wọn maa le ṣe atupalẹ awọn ilana ati igbesẹ ijọba, a nilo awọn ọba alaye ti wọn o ni i fepo-bọyọ lati gbẹnusọ fawọn eeyan wọn, tori naa, gbogbo wa pata la ni ipa kan sikeji lati ko ninu ọrọ to delẹ yii, a si gbọdọ ṣe e pẹlu gbogbo okun wa ni.

“Ṣugbọn mo ro pe nnkan to kọkọ ṣe pataki ju lọ ni pe ka kunlẹ adura fun orileede wa pe ki ẹnikẹni to ba bọ sipo aarẹ, gomina, sẹnẹtọ, awọn aṣoju-ṣofin, atawọn olori kaakiri, le jẹ olori rere.

“Gẹgẹ bii Musulumi ati ọmọ orileede yii, o yẹ ka maa ran ara wa leti pe ki i ṣe bo ṣe yẹ ki nnkan ri lorileede yii niyi, o yẹ ko daa ju bo ṣe ri yii lọ. Tori naa, asiko yii kọ lo yẹ ka tun yan olori kan tori pe wọn fun wa lowo, tabi tori ọmọ ibilẹ tabi agbegbe to ti wa.”

Bẹẹ ni Sanusi sọ.

Leave a Reply