Akpan niyawo oun ko ‘fain’ mọ, lo ba n ba ọmọ bibi inu ẹ lo pọ n’Itele-Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko kuku tiju, ko si fọrọ sabẹ ahọn sọ pẹlu, iyẹn ọkunrin torukọ ẹ n jẹ Ubong Williams Akpan. Bawọn ọlọpaa ṣe beere lọwọ ẹ pe ṣe loootọ lo n ba ọmọ bibi inu ẹ to jẹ ọmọ ọdun mejila lo pọ lo ni bẹẹ ni, ọmọ naa loun n ba sun bayii, nitori iya rẹ to jẹ iyawo oun ko fain mọ, o ti n darugbo!.

Itele-Ọta, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti mu Akpan, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49), lọjọ keji, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii.

Ọmọ rẹ obinrin to n ba lo pọ ni kinni ọhun su, lọmọ ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Itele-Ọta, pe baba oun ti fẹẹ fi kinni to fi daṣẹẹ oun gbẹmi lẹnu oun.

Ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa sọ fawọn ọlọpaa pe ọdun karun-un ree ti baba oun ti n ba oun lo pọ. O ni ọmọ ọdun meje pere loun wa ti baba naa ti n ba oun laṣepọ, ko si yee ṣe bẹẹ titi dasiko yii toun ti pe ọmọ ọdun mejila.

O fi kun alaye ẹ pe ibalopọ naa ko tẹ oun lọrun, ara oun ko si gba a mọ loun ṣe jade waa sọ fawọn ọlọpaa.

Ifisun ọmọdebinrin naa lo mu DPO teṣan yii, CSP Monday Unoegbe, lati gbe awọn ikọ rẹ dide lọ sile awọn Akpan.

Bi wọn ṣe mu baba naa ti wọn beere ọrọ lọwọ ẹ lo jẹwọ pe loootọ loun n ba ọmọ oun sun. O ni ko sohun to fa a ju pe iyawo oun ti n dagba, ko wu oun mọ, nitori ẹwa ti n ṣi lọ lara rẹ. O ni nigba to si jẹ pe ọmọ to bi foun wa nibẹ to duro rẹgi, iyẹn loun ṣe gbagbe iya, toun bẹrẹ si i ko ibasun fọmọ to bi foun.

Wọn ti mu ọkunrin yii ju si gbaga, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi to ALAROYE leti ṣe wi, bẹẹ ni wọn ti mu ọmọ rẹ naa lọ sọsibitu ti yoo ti gbatọju nitori ibasun ti baba rẹ n ko fun un.

Leave a Reply