Alaboyun kan atawọn mẹjọ mi-in jona ku nibi ijamba mọto n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Bi eeyan ba jori ahun, omije yoo da loju ẹ lọjọ Aiku, Sannde, opin ọsẹ yii, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, nibi ijamba ọkọ to mu ẹmi alaboyun kan ati eeyan mẹjọ mi-in lọ niwaju papakọ ofurufu to wa niluu naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ ọjọ Aiku, ni iṣẹlẹ naa waye, nibi ti ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan to ni nọmba iforukosilẹ LRN 787 FE, ati  ọkọ akero Toyota Hiace kan ti kọ lu ara wọn, to mu ki ina sọ. Eeyan ogun, ọkunrin mẹjọ ati obinrin mejila, lo fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn eeyan mẹsan-an, ọkunrin kan ati obinrin mẹjọ ni wọn  ku loju-ẹsẹ

Ninu ọrọ ajọ ẹṣọ alaabo oju popo, ẹka ti ipinlẹ Kwara, wọn ni ọkan lara awọn ọkọ to kagbako ijamba ọhun ko epo bẹtiroolu sinu ọkọ rẹ, eyi lo mu ki ọkọ naa gbina, ti iṣẹlẹ naa si lagbara kọja sisọ. Adari ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Owoade, fìdi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni wọn ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan jẹnẹra tipinlẹ Kwara to wa niluu Ilọrin, fun iwosan to peye. Wọn si ti ko awọn oku lọ sileewosan Olukọni Fasiti Ilọrin, eyi to wa ni Oke-Oyi, nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply