Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ajọ Sifu Difẹnsi ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ayederu dokita kan, Ọladiti Saheed Toyin, lori ẹsun pe obinrin alaboyun kan ku mọ ọn lọwọ lasiko to n gbẹbi fun un.
Saheed, ẹni ọdun mejilelọgbọn, to n gbe ni Ojule keji, agbegbe Lakewu, niluu Ọ̀rọ̀rúwọ̀, nipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi alakoso ajọ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Dokita Micheal Adaralẹwa, ṣe wi, akẹkọọ-jade ileewe ileewe girama ni Saheed, lati ọdun mẹfa sẹyin lo si ti ṣi ọsibitu kan to pe ni ‘Oluwatoyin Clinic’ siluu naa, to si tun n kọ awọn eeyan niṣẹ dokita nibẹ.
Nigba to n ka boroboro, Saheed ṣalaye pe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni obinrin alaboyun naa wa si ọsibitu oun pẹlu oyun oṣu mẹsan-an ati ọsẹ mẹta.
O ni obinrin naa ko lọ fun ayẹwo oorekoore (antenatal) nibi to kọkọ forukọ silẹ si latari ede aiyede kan to waye laarin oun (alaboyun) ati ọkọ rẹ.
Saheed fi kun ọrọ rẹ pe nigba to de ọdọ oun, oun yẹ ifunpa rẹ wo, o si kere pupọ, idi si niyẹn ti oun ṣe fun un loogun, oun si sọ fun un pe ko pada wa nigbakuugba ti ọmọ ba ti n mu un.
O ni lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọmọ bẹrẹ si i mu obinrin yii, o wa si ọsibitu oun, o si bimọ, ṣugbọn bo ṣe bimọ tan ni nnkan yiwọ, ti oun si gbe e lọ si ojulowo ileewosan kan nitosi, nibẹ ni wọn si ti sọ pe o ti ku ki oun too gbe e de.
Iwadii tun fi han pe ẹgbẹrun marun-un pere ni Saheed maa n gba lọwọ awọn ọmọ to n kọ niṣẹẹ ayederu dokita.
Adaralẹwa ṣalaye pe iwa ti Saheed hu ni ijiya labẹ abala ojilelọọọdunrun o le mẹta iwe ofin iwa ọdaran ti orileede yii n lo.
O kilọ fun awọn araalu lati ma ṣe pantete ẹmi wọn sọwọ awọn ayederu dokita, o si sọ pẹlu idaniloju pe Saheed yoo foju winna ofin lẹyin iwadii.